O so pe nitori pe ko se ni
to le ba won soro, to si je pe eni to ba gbawon lamoran latari imura asewo ti
won n mu kaakiri ilu n doju ti ise tawon yan laayo nitori pe eni to ba ba won
soro, won setan lati bu eni naa, ki sokoto jabo nidi e.
Eleso to ti le logun odun
nidi ise naa, to si je pe bo se je aafin lo je ko tete di gbajumo pelu awada
ati eebu e tun so pe ikokuko lo po ninu fiimu ti won gbe jade bayii.
O ni bawon fiimu naa ko se
ni ori, bee naa ni ko ni iru, ti ko si ogbon kankan teeyan le ri ko nibe
leyin teeyan ba fi aimoye wakati jokoo tii.
Ninu oro e lo ti so pe “Opo
awon eeyan lo ti n beere lowo mi pe ki lo de ti won ko fi ri mi ninu sinima. Ti
e ba sakiyesi daadaa, e o rii pe awon ta a jo pe egbe nidi ise yi ni won ko fi
taratara se e mo, ti won si ti n yago fun ise tiata. Idi ni pe, gbogbo wa la n
beru iru ise ti a ti fe e kopa ati pe iwa itan tawon omo ta a ni nidi ise naa
lasiko yi n ko ni ko mu ogbon dani. Ninu ile mi paapaa, kii se gbogbo fiimu ti
won gbe jade lasiko yi ni mo n wo nitori pe e ko le ri eko kan soso ko nibe
leyin ti e ba wo o tan.
“Opo awon osere obinrin ni
won kii mura to da a, to je pe imura asewo ni won n mu ninu fiimu, ati kaakiri
igboro. Nigba ti awa si ko ni obi won, a ko lanfaani lati ba won soro nitori
won kii gbo si wa lenu.
“E o le reti wipe kawon omo
ti obi won ko se awon nkan to ye ki won se lori mo won, ki won huwa to boju mu
laarin ilu. E o le ri awon omo to je pe ise tiata ni obi won n se, ko hu iwa
kiwa, tabi se isekuse, ko seese."
Nigba to n soro nipa nnkan
to n sakoba julo fun ise tiata, Eleso so pe “Eyi to tun je pabambari e, to n pa
ise tiata lara ni tawon to n se ayederu fiimu jade. Opo wa lo je pe ile
ifowopamo, kiyen banki lati ma lo n ya owo lati se fiimu jade, leyin gbogbo e,
a kii ri owo naa pada lati ko jo nitori awon to n sayederu ti gba a mo wa lowo.
“Igba kan wa to je pe mo mu
eni kan to se ayederu fiimu mi ti mo gbe jade, mo mu lorun owo ni, o si dunkoko
mo mi nigba naa wi pe ti m ba fi olopa gbe oun, toun si s’ewon, oun a pada wa
ba mi toun ba jade lati pa mi danu, nitori to so fun mi pe ise adigunjale loun
n se tele, ati pe nigba ti won pa awon elegbe oun, loun bere sii se ayederu
fiimu.
“Eyi lo fa a ti mo fi yanda
eni na pe ko maa lo. Ijoba lo le ran wa lowo nipa oro awon to n sayederu fiimu
jade. Ti ijiya to to ba wa fawon towo palaba won ba segi, iwa naa maa dinku
lawujo wa.”
No comments:
Post a Comment