Idi ti Alaafin se yan Gani Adams gege bi Aare Ona Kakanfo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 17, 2017

Idi ti Alaafin se yan Gani Adams gege bi Aare Ona Kakanfo

Latigba ti Oloogbe Oloye Basorun Moshood Kasimawo Abiola ti papoda lawon omo Yoruba ti n foju sona fun eni ti yoo tun pada gba ipo naa gege bi Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, ti ko si seni to mo eni ti yoo je.

Sugbon ileri tawon omo ile Yoruba ti n foju sona fun lati odun mokandinlogun seyin naa pada wa si imuse nigba ti Alaafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ti so o jade sita loji Aiku Sande to koja pe ko seni to tun kun oju osuwon lati gba ipo naa, bi ko se Oloye Otunba Gani Adams to je adari egbe OPC lorileede Naijiria. Gani Adams ni yoo je Aare Ona Kakanfo elekeedogun ti yoo je.

Bo tile je pe awuyewuye naa ti n jeyo latinu osu kefa odun yi pe Gani Adams ni won fe e fi ipo naa da lola latari awon ipa to n ko lati gbe orileede yi, paapaa asa ati ise Yoruba laruge lawon orileede kaakiri agbaye, to si tun n lewaju ogun lati ja fun eto omo Yoruba.

Sibe, ko seni to jeri si awuyewuye naa ninu Otunba Gani Adams tabi Alaafin Oyo lati so pe ooto oro ni, tabi wi pe awuyewuye ti ko lese nile ni, sugbon ti gbogbo e wa pada di otito oro pe Otunba Gani Adams ni ipo naa to si.

AWIKONKO gbo pe ibi ayeye odun kokandinlogorin ti Alaafin Oyo se lai pe yi ni won ti fun Otunba Adams ni iwe to fidi e mule, iyen appointment letter pe oun ni yoo gba ipo naa.

Alaafin so pe ninu awon adije marun fun ipo naa, olori egbe OPC naa lo kun oju osuwon lati gba ipo naa, toun yoo sip e ipade awon oniroyin lai pe yi lati fi kede e sita fawon eeyan.

Fawon ti ko ba mo, awon to ti je Aare Ona Kakanfo seyin ni Kokorogangan tiluu Iwoye Ketu; Oyatope tiluu Iwoye; Oyabi tiluu Ajase; Adeta tiluu Jabata; Oku tiluu Jabata; Afonja tiluu Ilorin; Toyeye tiluu Ogbomoso; Edun tiluu Gbogun; Amepo tiluu Abemo; Kurunmi tiluu Ijaye; Ojo Aburumaku tiluu Ogbomoso; Latosisa tiluu Ibadan; Ladoke Akintola tiluu Ogbomoso ati Moshood Abiola tiluu Abeokuta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI