Egbe EGBAGA ko ile iwosan fawon ara agbegbe Olodo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 23, 2017

Egbe EGBAGA ko ile iwosan fawon ara agbegbe Olodo

Beeyan ba de ilu Olodo nijoba ibile Odede lojo Abameta Satide to koja yii, to ri tawon eeyan n jo, ti won n yo, yoo mo pe idunnu lo subu lu ayo won, nitori lara awon idagbasoke ti won ti n reti lati ojo to ti pe ni.

Lojo Abameta Satide naa ni egbe kan to wa fikale siluu Georgia lorileeede Atlanta, iyen egbe Egba Association of Georgia in Atlanta (EGBAGA) fa kokoro ileewosan igbalode ti won sese ko pari fun won le won lowo lati maa lo o.

Fawon to ba mo ilu Olodo ati agbegbe e daadaa, won yoo mo pe o ti le logun odun ti won ko ti ni ileewosan, eyi to je pe ilu Abeokuta ni won n gbe awon alaisan lo lati loo gba itoju.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won so pe lara awon iya to n je won lagbegbe naa, osibitu je eyi to se pataki julo, sugbon ti enu won ko gba ope lojo naa latari bi inu won se dun to.

Ohun taa tun gbo ni pe, egbe EGBAGA yi tun se ayewo ofe fawon araalu naa ati agbegbe e, ti won si tun fawon to niloo oogun lawon oogun to le dena aisan tabi aarun to n ba ilera ara won finra.

Nigba to n b'AWIKONKO soro lojo naa, alaga ijoba idagbasoke Orile Ilugun, Arabinrin Mofoluke Soremekun tawon eeyan tun n pe ni ayon-ledi (Iron Lady) so pe idunnu n la lo subu lu awon ara agbegve naa nitori pe nnnkan tawon ti n foju sona lati ojo pipe ni.

Soremekun je ko di mimo pe lara awon ileri toun se fawon eeyan lakoko ipolongo idibo to gbe oun wole ni lati mu idagbasoke ba agbegbe naa, ati lati pe awon omo bibi ile naa to wa loke okun wa sile lati wa a da ise sile, paapaa ki won wa a mu ilosiwaju ba ilu won.

Obinrin naa tun so pe kekere ni nnkan ti won rii pe egbe EGBAGA se e, nitori pe ise si n lo labele lati rii pe awon ara agbegbe oun je mudunmudun ijoba awaarawa to wa nita yii, paapaa lasiko ijoba Gomina Ibikunle Amosun to je ore araalu.

Ninu oro ti e, Kabiyesi ilu Olodo, Oba Ebenezer Babatunde to je Olu-Keesi tiluu Olodo nigba to n b'AWIKONKO soro so pe beeyan ba gun esin ninu oun, eni naa ko nii kose, ati pe oun ko le so binu oun se dun to latari osibitu igbalode naa.

O loun ti tan awon ti yoo maa mojuto osibitu naa losan ati loru ki awon dukia naa le wa labe aabo. Bee lo so pe  kawon araalu naa ri daju pe won n sabojuto e daadaa e, ki won le lo o lalope.

Kabiyesi nigba to n gboriyin fegbe EGBAGA, o so pe egbe to ni ero rere lokan legbe naa, nitori ti won nife awon omolakeji won, ti kii se pe bamubamu ni mo yo ni won n se e, o wa fi adura kun fun won, to si ro awon omo ile Yoruba to ku lati wo awokose won maa fi mu idagbasoke ba ilu ati orileede won.

Saaju akoko ni alukoro egbe naa,Ogbeni Olanrewaju Lemboye so pe egbe won wa lati gboruko awon omo bibi ilu Egba to n gbe niluu Atlanta Georgia ga, ki won si fi gbe ilu won laruge.

O ni kekere ni eyi tawon se yi bo tile je pe kii se akoko iru e tawon maa se, nitori tawon tun n gbiyanju lati se nkan to ju ileewosan naa lo silu Olodo, paapaa Abeokuta, ati pe lodoodun lawon n se ipade gbogboogbo lati tun pinu nnkan min in tawon fe e se.

Nigba to n soro lori idi to fi je pe Olodo ni won ko ileewosan naa si, Olanrewaju so pe nigba tawon kaakiri ilu Egba lawon rii pe orisirisi ileewosan lo wa nibe, sugbon to je pe ileewosan kan soso to wa ni Olodo ku die kaato, ko bojumu rara, eyi lo fa a tawon fi pinnu lati gbe ise naa lo sibe.

Lara awon igbimo EGBAGA ni Ogbeni Omokayode Elerunwon to je Alaga; Arabinrin Adeyi to je igbakeji; Omoba Akindele to je akapo; Arabinrin Adebowale to je akowe.

Awon min in tun ni Oloye Femi Akindele; Lanre Bada; Arabinrin Elerunwon ati Ojogbon Arabinrin Adeniyi toun je iya isale (Matron).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI