E je ki ise yin tubo fese rinle sii - ijoba ipinle Ogun gba VSO lamoran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 27, 2017

E je ki ise yin tubo fese rinle sii - ijoba ipinle Ogun gba VSO lamoran

Ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun yi gba ajo eso ojulalakanfinsori, fijilante tipinle naa, iyen Vigilante Service of Ogun state (VSO) lamoran wi pe ki won je ki ise aabo ilu ti won n se tubo fese rinle sii lawujo.

Jide Ojuko ati Soji Ganzallo
Oloye Babajide Ojuko to je Komisana foro ijoba ibile ati oye ji je nipinle Ogun lo soro yi lakoko to n si aso tuntun, iyen yunifoomu tuntun loju eegun fun ajo naa, eyi ti won yoo maa lo bayii lojo Tusde ose to koja niluu Abeokuta.

Nigba to n soro nipa idi ti won se ronu kan yunifoomu tuntun naa fun won, Oloye Ojuko so pe pelu aso yunifoomu tuntun yii, idaniloju wa wi pe ise won a tubo fese rinle sii, ti imura won yoo si tun dun un wo loju awon araalu, paapaa nipinle Ogun ati agbegbe e.

Ninu oro e, o so pe "Pelu aso tuntun yii, a n fe ise takuntakun ti yoo dara ju ti ateyunwa lo. Awon araalu ma a fe ri awon ise ati ipa ti e fe e ko, imura yin ati igbese yin nipa ona ti e fe maa gba sise lona wi pe ise ti e n se ye e yin pupo.

" Mo wa a fi asiko yi pe yin nija wipe ki e tubo gbaju mo ise yin, ki ensi fowosowopo pelu ijoba ipinle Ogun lati gbogun ti iwa odaran nipinle naa ati agbegbe e."

Saaju akoko yii ni oga agba fun ajo naa nipinle Ogun, Ogbeni Soji Ganzallo so pe bo tile je pe loore-koore lawon n se idanilekoo fawon osise ajo naa lati le je ki won mo pataki ise won, ati ona ti won yoo lo lati sise won, sibe awon ko bii dawon duro nitori pe emi ati dukia awon araalu lo je awon logun.

Ganzallo wa rawo ebe sawon araalu wi pe ki maa fi oro odaran to ba n sele ladugbo ati lagbegbe won to awon osise naa leti, paapaa nibi ti won ba fura pe o je ahamo awon odaran lati le rowo to won.

Titi di bi e ti n ka iroyin yi ni inu awon osise ajo Fijilante nipinle Ogun, iyen Vigilante Service of Ogun State (VSO) si fi n dun lori yunifoomu tuntun tijoba tun sese fowo si fun won lai pe yii.

Ohun taa gbo ni pe lara igbese lati satunto ajo naa ki ise ti won n se tun le tubo maa lese jare siwaju sii, ati lati le tubo dun un wo loju awon araalu lo fa a ti won fi pinu yunifoomu tuntun naa.

Kii se eyi nikan, a gbo pe lati sagbelaruge ati lati le ji ki ajo VSO tubo gbayi loju awon eeyan pelu nnkan to fa a ti won fi ni dandan, a fi ki won gba yunifoomu tuntun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI