A fi ki awon araalu maa fura bayii, latari awon to pe ara won ni sarin-sarin, iyen awon to n sa irin kaakiri igboro, to je pe won n fi ise naa boju ni, to si je pe jaguda baba ole ni won.
Won ni
ojo gbogbo ni ti ole, ojo kan ni ti olohun, eyi lo lo ni ibamu pelu bi owo awon
araalu se te odomokunrin eni odun mokandinlogun (19) to n gbe ladugbo Asero niluu
Abeokuta, ti won so pe o loo ji ero amunawa jenereto.
Ka ni
Kabiru ti won so pe ise awon to n sa irin kaakiri igboro ba mo pe asiri oun maa
tu lojo Abameta Satide to koja lo lohun ni, o seese ko ma jade lojo naa, tabi
ko ma pinu lati ji jenereto to sakoba fun un.
Ohun ta a
gbo ni pe ni nnkan bi aago mejila aabo osan ojo naa ni won so pe owo awon
araadugbo Elite ni Idi Aba te Kabiru lakoko to n gbe jenereto naa sa lo.
AWIKONKO
gbo pe awon araadugbo naa to fura sii da a duro lati beere ibi to ti ri ero
amunawa jenereto naa, sugbon to so fun won pe ki lo kan won pelu igbesi oun.
Oro ti
won lo o so jade lenu yi gan an ni won so pe se akoba fun, ti won si pariwo ole
le e lori. Nigba ti Kabiru rii pe awon eeyan naa ko mu oro naa ni kekere foun,
lo je ko paro pe owo okan lara awon onibara oun loun ti ra a.
Eyi lo fa
ti won fi so fun un pe ko mu awon lo sodo onibara e naa, sugbon to ba won
lagidi pe oun ko le mu won lo sibe, ki won je loun ma a lo.
Lesekese la
gbo pe won ti bere sii luu, ko too jewo fun won pe nise loun jii gbe, ki won se
oun jeje, ki won si daso asiri boun, sugbon iro to pa fun won lo tun je ki won
tun bere sii lu lalubami.
AWIKONKO
gbo pe lesekese ni won ti ranse pe awon ajo Fijilante ojulalakanfinsori ipinle
Ogun, iyen awon VSO ti ekun Abeokuta Southeast lati fi to won leti.
Okan lara
awon araadugbo naa, Lekan nigba to n b'AWIKONKO soro so pe kii se akoko ti
Kabiru maa ji nnkan re e, ati pe o ti pe tawon ti n wa, sugbon ti Olorun fa a
le awon lowo lojo naa.
Oludari
Fijilante ekun naa, Ogbeni Mojeed Aderolu nigba to n jeri sisele naa losan ojo
Monde to koja, o so pe ibi ibura fawon oloye tuntun ti ajo naa sese yan loun wa
ti won fi ranse soun, lesekese loun si ti ran awon omose oun loo sibe.
Mojeed ni
awon ti gbe Kabiru lo si Olu ileese won lati tubo loo foro wa lenu wo, nitori
tawon ko lase lati gbe e lo si tesan olopaa lai je pe oga awon Soji Ganzallo mo
si.
AWIKONKO ba oga agba naa, Ogbeni
Ganzallo soro lati fidi oro naa mule, nnkan to so ni pe iwadii si n lo lowo,
tawon yoo si gbe e lo si tesan olopaa lati tesiwaju ninu ise iwadii won.
No comments:
Post a Comment