Die lo ku ki won pa okunrin ti won ka oku eeyan lowo e ni Mowe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 16, 2017

Die lo ku ki won pa okunrin ti won ka oku eeyan lowo e ni Mowe

Bi kii ba a se opelope ori to ko arakunrin kan ti a ko tii mo oruko e titi di asiko ti a n sakojopo iroyin yi lowo, ti won so pe won ka ori eeyan atawon eya ara eeyan lorisirisi ni apo to gbe dani lagbegbe Mowe nipinle Ogun lojo Tosde ose to koja yii, o seese ki won ti luu pa nitori ta a gbo pe okan lara awon to n feeyan soogun owo ni won pe e.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won so pe awako kan ti okunrin naa wo lo sakiyesi pe nnkan to wa ninu apo ti okunrin naa gbe lowo jo eya ara eeyan, ati pe oorun to n jade ninu apo naa yato si idoti lasan tabi ajeku ounje.

A gbo pe awako naa beere lowo okunrin yip e ki lo gbe dani, sugbon to so pe ko si nnkan to kan, ati pe idoti lasan lo wa ninu apo to wa lowo oun, sugbon nigba ti okunrin awako naa rii pe onibara e yi ko fe e jewoo, to si fura pe o seese ko je pe eya ara eeyan lo wa ninu apo naa, lo ba paaki moto e segbe kan, to si pariwo soke pe kawon eeyan gba oun.

Lesekese la gbo pea won to n koja lo ti duro lati mo nnkan to n sele, nigba ti won si beere lowo okunrin naa pe ki lo gbe dani, to so pe idato lasan lo wa nibe, eyi lo fa a ti won so pe ko da nnkan to wa ninu e sile, toun naa si da a sile.

AWIKONKO gbo pe nise lawon eeyan kawo sori pariwo sita wi pe owo awon tun ti te okan lara awon to maa n ji eeyan gbe pa lati fi won soogun owo, ko too di pe won bere sii luu.

A gbo pe bi okunrin naa se fe  maa salaye bi ori oku atawon eya ara naa se je lawon eeyan ko ti e fe e gbo oro lenu e, ti won ja sihoho omoluabi , ki won to bere sii luu, to ku di e ki won dana sun.

Enikan lara awon toro naa soju e la gbo pe o ta awon olopaa lolobo, tawon naa si gbera leskese lati fa a foju won to o. Nigba ti won de be, ni won mu okunrin naa lo tesan won, tawon eeyan si n pariwo pe a fi ki won pa a.

Tesan naa la gbo pe okunrin naa ti salaye fawon olopaa pe kii se pe oun paayan, tabi wi pe oun ji eeyan gbe lati soogun owo. O salaye fun won pe ile kan loun sese ra sagbegbe Arigbawonwo, toun si rii wi pe won ti sin awon oku sibe.

O loun ti ranse pe awon to ta ile naa foun, nipa bi won se fe e se oku to wa nibe, nitori pe oun ko le ko ile sori ile ti won ti sinku si. Awon ebi oku naa ni won ni koun loo wuu, koun si loo wa ibi toun maa sin in si.

A gbo pe nnkan to fa a ni yii, tokunrin naa ko fi ronu lati ranse pea won olopaa, ko le fi to won leti, ati pe ko ronu wi pe oro naa le se akoba nla foun, ni ko je ko ronu lati fi to awon agbofinro leti, toun naa si lo o wu oku.

Ibi ti o ti n gbe e lo ibi to ma a sin oku naa si lawon eeyan ti rii, to je pe eleda e la gbo pe o ko o yo lowo iku aitojo ojiji ti ki ba pa.

Ohun ohun ta a gbo ni pe okunrin naa ti wa ni eka olu ileese olopaa to n ri soro ajinigbe ati egbe okunkun to wa ni Eleweran Abeokuta, nibi ti won ti n foro wa a lenu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI