Bi
kii ba a se pe awon olopaa Ijebu Ode tete dide lati loo koju awon adigunjale ti
won so pe won maa n da awon eeyan lona lopopona Sagamu si Ore, iyen lagbegbe J4
ipinle Ogun, o seese ki won ti na papa bora nigba ti sose won bi won se maa n se
e.
Gege
b'AWIKONKO se gbo, ni nnkan bii aago mesan aaro ojo Eti Fraide ose to koja la
gbo pe awon adigunjale naa lo lati lo dawon eeyan lona, ko too di pe awon to ri
won ta awon olopaa lolobo.
Ohun
ta a gbo ni pe lesekese ni oga olopaa Ijebu Ode ti lewaju awon iko e lati loo
koju won, ibi ti won ti n gba dukia awon to ko si panpe won ni won ti ri won.
A
gbo pe bawon adigunjale naa ti se ri moto awon olopaa ni won ti koju ibon si
won, toro si di boo lo o yago laarin awon olopaa atawpon odaran naa, ko too di
pe awon meji fara gbota, ti won si ku lesekese.
AWIKONKO
gbo pe owo te okan lara won nigba tawon to ku na papa bora.
Odomokunrin
towo te naa, nigba to n soro so pe oun ko si lara awon adigunjale naa, ati pe
awon kan ni won pe oun jade kuro ninu Mosalasi toun wa lagbegbe J4, ko too di
pe won mu oun.
Nigba
to n jeri soro naa ni tesan olopaa Ijebu Ode, Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu so
pe looto ni, ati pe lara awon ero ja oloro ti won ri gba lowo won ni ibon ilewo
kekere kan, ero ibanisoro kan atawon ero to n pa feere moto, (carton of car
sound protector).
Iliyasu
so pe okan lara awon adigunjale towo te naa ti wa ni akolo awon, nibi tawon ti
n foro wa a lenu wo. O ni leyin iwadii awon, towo si ti te awon toku e to salo,
ileejo ni won yoo gbeyin si.
No comments:
Post a Comment