Ileewe ni Asmau dagbere, lo ba sa lo sile oko afesona e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 16, 2017

Ileewe ni Asmau dagbere, lo ba sa lo sile oko afesona e

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lawon alagbato omodebinrin eni odun meedogun, Asmau Ajibade ti won so pe John ati Moses ji gbe lojo keedogun osu kesan an to koja yi si fi wa ninu idunnu latari bawon araalu se n so pe o see se ko je pe awon ni won gbimo papo lati ji omo naa gbe fi soogun owo.

Asmau Ajibade
Alaaji Raufu Adetona ati Alaaja Ajarat Adetona to n gbe ni Area 8, Road 810, Block AM, Plot 18, OPIC Estate, Agbara, ipinle Ogun ni won so pe awon ni won n toju Asmau Ajibade ti won so pe ileewe girama ti Agbara, iyen Agbara Community Junior High School lo n lo, ati pe eka ikekoo keji, iyen JSS2 lo wa, ati pe odun kokanla to ti wa lodo awon alagbato yi re e leyin tawon obi ti ko ara won sile.

Ohun ta a gbo ni pe ileewe ni Asmau ti won so pe omo osu mefa lo wa nigba ti baba e ku dagbere laaro ojo naa lai mo pe odo ololufe e lo sa lo, nigba to si to asiko to ye ko pada sile, leyin ti won ti jade nileewe, la gbo pe won ko rii, latigba naa ni won ti bere sii wa, ojo keji ni won lo beere e nileewe, sugbon tawon yen so pe awon ko rii.

Lesekese ni won ti loo foro naa to awon olopaa Agbara leti, ti won si bere igbese lati wa Asmau jade nibi to ha si. AWIKONKO gbo pe lara awon araadugbo ti e ti n fimu kun labele pe o seese ko je pe Raufu ati iyawo e Ajarat ni won gbimo papo lati fomo naa soogun owo, ti won si fe e maa dawon olopaa laamu.

Nigba ti won lasari maa tu sita, okan lara awon to sunmo awon alagbato Ajarat ni won sa dede rii lagbegbe Oko Afo ni Badagry nipinle Eko lojo Abameta Satide to lo lohun nibi to ti n fese pale kaakiri, lesekese ni won so pe eni naa ti ranse pe Raufu ati Ajarat lori aago wi pe awon ri Asmau, tawon yen si so pe won ko gbodo je ko lo.

Ohun ta a gbo ni pe bi Asmau se ri eni naa lo ti fe e sa lo, tiyen si so pe oun ko nii so fenikeni, ko too di pe o gba lati pada wa lojo keji, ko si pe ti won so pe awon alagbato naa fi de lati wa a mu, ti won si foro wa a lenu wo, ko to o jewoo fun won pe Moses ati John lo gbimo po lati gbe oun salo.

Asmau jewo pe Moses ti won so pe ise awon to n ran bata lo n se lo je koun mo John, tawon si n fe ara won, o so pe soobu Moses ti lo o pade John to n sise sikioriti n’Igbo Ekerin, Agbara laaro ojo naa, to si gbe oun lo sile e ni Oko Afo nibi toun ti lo ojo merin pelu e. O ni nigba ti John ko tete foun sile, loun fi salo mon on lowo.

Nigba to n soro, Alaaji Rauf Adetona so pe inu oko loun wa nigba tiyawo oun pe oun lori foonu pe oun ko ri Ajarat latigba tawon akegbe e ti jade nileewe, latigba naa lawon ti n wa. O so pe Moses so fawon pe odo oun lo ti se bata e ko to maa lo sileewe lojo naa, lai mo pe oun gan lo gbimo ji omo awon gbe.

Raufu je ko doi mimo pe Asmau lo mu awon lo sibi ti John ti n sise sikioriti tawon si fi olopaa gbe e nibi to ti jewo pe oun ati Moses lawon jo sise naa. O lawon mejeeji ni won ti wa lago olopaa bayii.

Agbenuso funleese olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa so pe owo awon ti ba John ati Moses nitori pe awon ni won gbimo papo lati ji omolomo gbe pamo lati maa ba a sun. O ni iwadi si n lo lowo ati pe o see se ki won foju bale ejo nitori iwa ti won hu ko yato si ti ajinigbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI