Asiri iku to pa Funke Abisogun, osere tiata Yoruba nni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 24, 2017

Asiri iku to pa Funke Abisogun, osere tiata Yoruba nni

Bo tile je pe ibanuje nla niku okan lara awon gbajumo osere'binrin tiata nni, Funke Abisogun si n je fawon osere tiata egbe kaakiri orileede Naijiria to fi mo ole okun titi dasiko ti e ka iroyin yin, sibe orisirisi iroyin la gbo pe wi pe o fa iku obinrin naa.

Iyalenu nikuu Funke si n je fawon eeyan nitori pe asiko tawon eeyan si n ki fun ti omo tuntun to sese bi, lo dagbere faye, to si tun ti ko opolopo awon osere tiata egbe e sinu ironu nla bayii.

Ojo kerin ti Funke Abisogun, to tun je iyawo okan lara awon oludari ati olootu agba nidi ise tiata, Taofeek Al-Hassan Abisogun ta teru nipa lojo Aiku Sande to koja yii.

Okunrin kan, Tunde Yusuf to je aburo Taofeek Al-Hassan lo fi iroyin naa sita lori ero ayelujara, tawon eeyan si ti bere sii ba won kedun. Bee naa ni gbajumo osere'binrin nni, Ayanfe Adeyinka naa baraje pupo nigba tiroyin naa te e lowo.


Ayanfe Adeyinka ko o sori ero ayelujara Facebook e laaro ojo Monde to koja wi pe ibanuje nla niku iyawo oga oun je foun nitori toun ko roo ti tele.

O so pe Funke nikan lo maa n gbo oro oun, paapaa nigba ti oko e, Taofeek Al-Hassan ba se nnkan to dun oun ninu, to si maa ba won pari. Ayanfe Adeyinka so pe ko seni toun tun le fi ejo oga oun sun mo, nigba ti alaforo lo ti papoda. Bee lo tun so pe oun ko le gbagbe awon asiko tawon jo lo papo, paapaa lakoko to ya fiimu e, Olowo Sile lowo.


Funke tawon eeyan tun n pe ni iya Korede la gbo pe aisan kan ti a ko tii gbo nipa e lo seku pa a.

Lara awon fiimu ti Funke tun ti kopa ni Ajofeebo ati Olowo Sile to ko funra e.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI