Wasiu ati Azeez to yinbon fun DPO olopaa ti wa latimole olopaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 23, 2017

Wasiu ati Azeez to yinbon fun DPO olopaa ti wa latimole olopaa

Bo tile je pe Wasiu Ganiyu ati Azeez Komolafe ti won ni ogbologbo adigunjale ni won si wa nibi ti won ti gbategun itura logba olopaa to wa ni Magbon, Abeokuta nipinle Ogun, ti olori won, Mungo Park si ti soda sorun alakeji, sibe awon olopaa si n wa awon odaran to tu ti won so pe won na papa bora pelu ota ibon lara won.
 
Gege bi ohun taa gbo, awon adigunjale yi ni won so pe won yinbon fun DPO olopaa Ogbere, Ogbeni Adeyinka Akingbade lakoko ti won koju ija sira won ninu ogba oteeli kan lagbegbe Itele-Ijebu lose to koja.

Won lawon kan lo ranse sawon olopaa Ogbere pe awon adijunjale ti wo oteeli naa, won si n se awon eeyan to wa nibe nisekuse, eyi lo fa a tawon olopaa fi gbera lati loo koju won.

A gbo pe bawon adigunjale naa se rii pe awon olopaa ti de, ni won ba doju ibon ko won, nibi ti DPO naa ti fara gbota, to si subu lule, eyi lo fa ti won lawon olopaa to ku fi sa asala fun emi ara won.

Nise loro di boolo o yago lasiko naa, nitori taa gbo pe fun bii wakati kan aabo ni opopona fi da, tawon eeyan fori won pamo sinu ile, ati kooro.

Bi komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu se gbo sisele naa, ati pe DPO tun fara gbota, lo pase pe oun fee ri awon odaran naa laarin iseju merinlelogun, to si gbe ise naa le awon olopaa SARS lowo.

AWIKONKO gbo pe ko ju wakati mefa lo ti Komisana pase fun won ni won lasiri won tu sawon olopaa SARS lowo nibi ti won wa, nibe ni won tun ti doju ibon ko ara won, nibi ti won ni ota ibon ti ba Mungo Park to je olori won, to si ku lesekese, sugbon ti won ba Wasiu ati Azeez.

Komisana olopaa, Iliyasu so fawon oniroyin pe ibon AK 47 meji to gba ota ibon to to ogofa (120) ni won ri gba lowo won. O lawon to ku salo salo, ti iwadii si n lo lowo lati ri won mu.

Bee lo gbawon araalu lamoran paapaa awon osibitu lati fura lasiko taa wa yi, nitori pe ti won sakiyesi eni to gbe ota ibon wa sodo won, ki won tete fi to ileese olopaa leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI