Wahala nla n bo fun Naijiria lojo iwaju – Baba Alakoso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 9, 2017

Wahala nla n bo fun Naijiria lojo iwaju – Baba Alakoso

Olori ijo Kerubu ati Serafu onisokan, iyen ijo Cherubim and Seraphim Unification lagbaye, Woolii, Ojogbon Dokita Solomon A. Alao ti so pe bi awon olori Naijria ko ba a sora lati wa nnkan se soro awon odo to n kekoo jade ileewe giga, ti won o ri iwe eri won fi sise se, wahala nla lo doju ko orileede yi lodun mewaa sigba taa wa yi, ati pe awon asiwaju wa si niloo idanilekoo to ye kooro lati dekun wahala ojo iwaju naa.

Wooli, Ojogbon Solomon Alao tawon eeyan tun mo si Baba Alakoso soro yi lai pe yi ninu ofiisi e to wa ni olu-iya ijo naa to wa niluu Ibadan lakoko to n b’AWIKONKO soro latari awon nnkan to ri nipase bi nnkan se n lo si lorileede yi, ati nnkan to sakiyesi ninu ijoba Aare Muhammadu Buhari.

Olori ijo naa so pe “A ni lati la awon olori wa loye, iyen nipa idanilekoo to ye kooro pelu bawon odo se n kekoo jade ileewe giga fasiti, poli ati koleeji lasiko yi, to je pe won o ri ise fi iwe eri won se. Laarin odun mewaa sigba taa wa yi, wahala nla n bo. To ba je bo se ma ri niyen, ko ri be e.

“Sugbon, mo ro pe atunto lo le e fori ko wahala nla yen. Opo awon orileede ni won ti de ibi to ye ki won de, ti iru awa yi si n wo won loke, idi ni pe won ni awon olori to ye, ti won si kun oju osuwon lati sise ti won gbe le won lowo.”

O ni kii se pe kaka kawon omo Naijiria dide lati ja fun eto won, to je pe Olorun ni won n ke pe lo n fa a ti a fi bara wa nibi taa wa lonii, sugbon nnkan to fa a ni pe a ti gbe esin sori ju bo se ye lo, eyi ti ko si ye ko ri be e.

Ninu oro e, o so pe “Mi o ni so pe nitori pe awa omo Naijiria, kaka ka dide lati ja fun eto wa, Olorun la n ke pe lo fa a, taa fi bara wa nibi ta a wa lonii. Iru ijoba to to si wa la ni lonii nitori pe a o se awon nnkan to ye ka se.

“Nnkan meji lo fa a, Onigbagbo ni mi, mo si n waaasu ihinrere, sugbon esin ta n sin gbodo je lati okan wa wa, kii se pe ka gbe e sori tawon eeyan yoo fi mo iru esin ta n sin. Mo fe e ri lojo iwaju lorileede yi, to je pe nise la ma maa beere lowo ara wa pe se Musulumi ni e ni, abi Kirisiteeni.

“Obasanjo gbiyanju lati se e, sugbon won o gba a laaye lati se e. Eyi lo fa a to je pe nigba tawon eeyan pemi nija pe ki loo de ti mo fi sagbateru Buhari lakoko ipolongo idibo odun 2015, nnkan ti mo so fun won ni pe, eni to maa se olori mi ko kan mi, nnkan ti mo fe ni eni to maa gbe ounje siwaju mi.

“Ibi ti a ti padanu gan an ni yii, idi si re e, to fi je pe nigba to ba di pe ka maa fi oselu tan ara wa lodun 2019 tidibo ba fe e de, awon oloselu a lo maa fawon ti ko lowo ni eedegbeta (500) naira lati dibo fun won, tawon naa ko si nii ro o leemeeji lati dibo fun won lai mo pe ojo ola won ni won n ta danu yen. Won o ni ronuu iya ti won maa fi je won ti won ba wole tan.

“Igba ta a ba dide lodi si iru awon ironu bayii la ma a to se aseyori, lai je be e, wahala to n koju wa yi a si maa tesiwaju lo titi ayeraye ni. Awon ti o ye ki won wa nijoba ni won wa nibe nitori eleyameya ati igbagbo esin ti won n se.

“Ti m ba ni agbara, ma a fun (squeeze) oro esin debi pe ko nii je nnkan babara ti a ma maa gbe pari bi a se n gbe yii. Onikaluku ma lo ma a sin nnkan to ba wuu, yala to ba je igi leeyan mon on sin, aaye gba a, sugbon ko sa a ti mo bi Naijiria se maa di nla. Opo awon eeyan to n lo soosi lo je pe ise iyanu ni won lo n wa nibe, ko si nkan min in.”

Nigba to n soro fun AWIKONKO nipa idakureku ina olojoojumo ta n foju ri, agba Wooli naa so pe “Mo ti figba kan so ri pe Ina maa da lorileede yi ti a ba lo ona eburu. Lona wo? Ma a se ofin pe osise ina tabi osise ijoba eyokeyi ko gbodo lo ero amunawa jenereto nile tabi ofiisi e, ko da a ni Aso Rock, Abuja. Nigba ti won bar ii bi iya naa se po to, ona abayo a yoju.

“Ojuboro ko se e sejoba orileede Naijiria bi a ba fe ki ilosiwaju wa. Eni to ba ko ile to ju iye owo to n wole fun un lo, mo ma a koko gbese le e, ko to o di pe o wa a salaye ibi to ti ri owo fi ko iru ile nla be e. Awon eeyan le so pe apase ni mi, sugbon eni to ya were die (semi-lunatic) lo le se ijoba Naijiria. Bi a ba bere sii pe ara wa jokoo, iwa jegudujera ma atan nile patapata, nitori pe iwa jegudujera ni ipile isoro wa.

Baba Alakoso tun so pe nise lo ye kawon araalu ma a pe akiyesi awon ajo to n ri soro sise owo ilu mokumoku bii ICPC ati EFCC sawon olori ijo to n lo moto nla, to n gbe ile nla, awon to n lo baluu (Jet) ati beebeelo, ki won sig be won sinu iwe iroyin kaakiri lati foju won han.

Idi ni pe, opo awon to n foruko Olorun boju yi lo je osole ni won se, to je pe eeyan ni won fi n rubo, ko too di pe won lokiki. Bi won se wa ninu soosi naa ni won wa ni mosalasi.

Ninu oro e, o so pe “Mo ti n so lopo igba pe to ba je emi ni Buhari, opo awon to n pe ara won l’ojise Olorun to n lo Jeeti lo ma a wa lewon bayii. Mo maa beere lowo e, ibi to ti ri owo fi ra a. Opo ninu won lo je pe olori ajinigbe ni. Mi o fi oro ara mi se igberaga, beeyan ba fun mi lowo to ju iye to n wole fun un lo, mi o ni gba a lowo, ki n to o gba, mo ni lati koko beere ibi to ti rowo naa.

Siwaju sii, Baba Alakoso so pe, a nilo atunto (restructuring) lorileese yi. “Boya a fe tabi a ko, nnkan to da a ni ka wa ni isokan ti ko se e ya. Agbara ti United States of America ni lonii, bi won se po to nii. Naijiria dab ii omiran laarin Afrika lonii, bi nkan ba se po to, ni oja se maa po to. O maa fun eto oro aje lagbara.

“A o le maa ba a lo bayii. Asise kan soso ti a si n ni bayii ni pe a o tii se atunto to ye ka se, a kan n fi ti ori wa lo si oko iparun ni. Ijoba ologun lo ko wa si nnkan ta a wa lonii, nitori ti won so pe Federal Republic of Nigeria ni wa. Ijoba ologun orileede Naijiria (Military Republic of Nigeria) ni wa.”

Nigba to n sapejuwe isejoba Buhari lati odun 2015 sigba ta a wa yi, Baba Alakoso so pe “Nigba ti mo lo o ba lodun 2015, mo so fun un pe o n lo si Aso Rock lati tun Naijiria se ni, mo si ro pe o ti gbiyanju agbara e. Mi o tii ri olori orileede to le koju olori ologun lojukoju bo se se. Ko seni to tun se iru e.

“Nnkan to n koju bayii, mo ro pe iwa jegudujera ti won ti ko wa si lo n ta pada wa ba wa. Mo gbadura pe o maa pari saa e pelu ayo. Lara nkan to ti se ni pe, iwa ajebanu ti dinku, eyi to je pe awon egbe oselu to ku, ara won ni won mo. Bo tile je pe oun naa ni lowo nitori pe egbe eye l’eye n wo to, sugbon kii se iru asiko yi to je pe opo awon eletan lo po ninu ijoba e, ti ko si nkan to le se sii.

“O rorun lati bu enu ate lu eeyan bi kii ba a se eni naa lo gbe eru lorii. Mi o fe ma a daruko, Buhari n gbiyanju agbara e gidi gan an, sugbon awon olori wa ko fun laaye lati se nkan to fe e se. Efori ni won n fun un, nitori pe won fe e se tinu won, toun si so pe rara.

Bee lo so pe ojoola to dara si wa fun orileede Naijiria lojo iwaju, nitori pe ko seni to ba a figagbaga to ba di asiko naa, iyen bi gbogbo wa ba le forikori lati koju awon nnkan to n fiya je wa, paapaa latari aini isokan.

Baba Alakoso so pe nnkan ta a nilo ni ka ni olori to maa ni suuru lati gbo nnkan tawon araalu n fe. “Mo ri pe lojo kan, atunto maa de ba orileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI