Saheed ati Fathia Balogun pari ija nibi ayeye ojo ibi Mista Paragon - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 30, 2017

Saheed ati Fathia Balogun pari ija nibi ayeye ojo ibi Mista Paragon

Ni Fathia ba foju pa MC Oluomo ati Muyiwa Ademola re

Tiyanu tiyanu lopo awon eeyan to wa nibi ayeye aadota odun ti okan lara Awon agba nidi ise tiata, Emir Kayode Akindina topo mo si Mista Paragon se niluu Abeokuta lojo Sande to koja lohun n wo awon osere ololufe meji ti won ti jawe funra won tipe, Saheed ati Fathia Balogun nigba ti won di mora won, to tun dabi eni pe won fee fenuko ara won lenu.

Fawon to ba mo awon  mejeeji yi daadaa, won a mo pe awon mejeeji kii fee foju kan ara won paapaa bi pati ba ti pa won po, eyi to mu ki Fathia ko lati yoju sibi ayeye aadota odun ti Saheed se ninu osu keje odun yi. Sugbon lose to koja yi lo da bi eni pe ija awon mejeeji fee pari.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO se so, okan lara awon osere egbe won, Toyosi Adesanya ni Olorun lo lati sise naa, won loun lo se sababi bawon mejeeji se di mo ara won, ti won si tun rerin sira won, debi to fee dabi pe won fee fenuko ara won lenu.

Ohun taa gbo ni pe Saheed Balogun lo koko debi ayeye naa, iyen bii wakati kan aabo ki Fathia naa too wonu gbongan DLK ti won ti sayeye naa nibi ti Alaaji Wasiu Alabi Pasuma ti korin.

Won ni bi Fathia se wole to loo ki awon eeyan to jokoo sori aga giga (high table) nibi ti Saheed, MC Oluomo, Dele Odule, Sefiu Alao, Omoba Muyiwa Adejobi to je agbenuso olopaa ipinle Ogun tele wa, bo tile je pe akoko naa lawon oniroyin ileese telifisan OGTV n foro wa Saheed lenu wo, sugbon to se bi eni ti ko rii oun ati MC Oluomo.

Bawon to ti n reti e lataaro se rii pe o ti wole, ni won ti sare loo faa pe ko maa bo lori aga tawon jokoo si nitosi pepe (alter). Bo se jokoo, egbe Olaniyi Afonja, Sanyeri nibi ti Muyiwa Ademola, Alaaji Kazeem, iyen Epsalum pictures, Afeez Owo atawon osere min in jokoo si.

Bo se ti jokoo la gbo pe Muyiwa Ademola toun jokoo legbe Sanyeri ti n rerin sii pe ko ki oun, sugbon ti ko wo odo e, to sebi eni pe oun ko Muyiwa ri, to si so mo Epsalum to je pe egbe Muyiwa gangan lo jokoo si. Gbogbo bi Fathia se n se ni Muyiwa n rerin muse pe o si maa ki oun, o kan n dibon ni, sugbon se lo dabi eni pe ironu awon mejeeji ko papo.

Bo tile je pe AWIKONKO ko rii gbo pe bo ya ija ti wa laarin won tele, sugbon ibeere ti won ni Epsalum ati Sanyeri n bi Muyiwa ni pe ki lo pa won po, ati pe se kii se pe Muyiwa ti denu ife ko Fathia tele ti ko gba fun un lo je ko maa binu sii, sugbon to ni ko le ye won.

Nigba to maa to bi iseju mewaa ni Muyiwa naa wa lo ogbon arekereke lati so pe ki won jo ya foto papo, sugbon oju ti Fathia fi woo bi eni pe ko digbaju ruu lori, tawon eeyan si tete fura pe ija ti wa laarin won tele, sugbon Erin ni Muyiwa tun fi daa lohun, nigba to dabi eni pe wahala Muyiwa fee po ju, lo ba gba fun lati baa ya foto, bi Sanyeri toun ti dide tele naa tun se sare wa niyen, ti won tu jo ya foto papo.

Oju buruku la gbo pe Fathia koko fi wo foonu Muyiwa to fee fi ya foto, ki Muyiwa too so fun n pe ko ma se be, ko gbiyanju lati rerin, loun naa ba fi tipatipa rerin ti ko denu e.

Ko pe ni Odunlade Adekola to dari ayeye lojo naa pe MC Oluomo pe ko waa so iye to fee fun olojo ibi, bawon eeyan si se n rerin soro ti MC n so ni Fathia n leju sii lookan bii pe olorun ko lo seda e.

Nigba ti MC naa se tan to sokale lo sibi ti Fathia atawon osere min in jokoo si, lo ba di mo Toyosi Adesanya atawon min in to wa legbe Faithia, se ni MC naaa sebi eni pe oun ko mo Faithia ri rara, bo tile je pe Faithia naa ti sare gboju segbe fun un bo se rii pe o n bo.

Won ni o seese ki Fathia tun ti gba a bo lodo MC Oluomo naa nitori pe bi MC se kuro nibi to ti soro ni Fathia naa ti dide lo sibe, lati loo ki Mista Latin ati Odunlade Adekola ti won jo pe MC soke odo won.

Ohun taa ri gbo ni pe, nnkan to sele yi lawon eeyan si n ronu nipa e lowo, ti won ni Toyosi ti loo pe Saheed to je oko Fathia tele pe ko waa kii nibi to jokoo si, bo tile je pe Toyosi ti so fun Fathia pe ko waa loo ki Saheed tele sugbon to loun ko le loo ki laye oun, ayafi to ba waa ki oun.

Won ni Saheed naa ti yari tele fun Toyosi pe oun ko le loo ki Fathia nitori pe igberaga e po, sugbon nigba to fee dabi eni pe wahala Toyosi po, ti ko si fee koro si lenu, lo ba gba lati tele loo kii.

AWIKONKO gbo pe bi Saheed se gba fun un, lesekese ni Toyosi ti fa a lowo, to si n sare woo lo sibi ti Fathia wa, oun atenikan ni won jo n soro lowo ko too di pe Saheed fowo ko o lorun, to si beere lowo e pe ‘bawo ni’, oju to maa gbe segbe lati woo eni to n ki oun, Saheed Balogun, oko e tele lo rii, iyalenu lo je fun un.

Fun bii iseju meji lawon mejeeji fi jo soro papo, ti won tun lo mo ara won, tawon eeyan si la enu sile pe fungba akoko leyin bi odun mewaa ti won ti ko ara awon sile, won tun sile pada rerin sira won.

Ko si nnkan tawon eeyan to wa nibi pati lojo naa n so bi ko se pe Toyosi Adesanya ni Olorun lo lati tun je kawon ololufe tele yi tun pada soro sira won, won tun lo seese kawon mejeeji tun pada maa se loko laya, sugbon tawon kan tun n so pe igberega Fathia ni ko fee je ki Saheed gba a pada gege biiyawo e, bo tile je pe won lo ti n wun Fathia ko pada sodo oko aaro e, Saheed.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI