Owo te Paul to ji omo mefa ni Calabar - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 8, 2017

Owo te Paul to ji omo mefa ni Calabar

Abeokuta lo ti n fi won s’eru

Nise lenu ya opo awon eeyan lojo Aje Monde ose to koja yi nigba tawon olopaa ipinle Ogun safihan okunrin odaran kan, Paul Alanla ti won lo n fawon omolomo soowo eru. 

Gege b'AWIKONKO se gbo, Siun nijoba ibile Owode Egba lowo olopaa ti te Paul lojo Abameta Satide to koja lo lohun, Iyen lojo kerindinlogbon osu to koja. 

Ohun taa gbo ni pe Ogoja nipinle Cross River ni Paul ti won ni ko nise meji ju ko maa fawon omolomo se owo eru lati maa fi won pawo sapo ara e. 

Won ni nigba tasiri e tu ni Calabar ni nnkan bi odun meta seyin, tawon olopaa si mu, lawon ebi e ti loo gba a sile, to si seleri pe oun ko tun ni pada sidi ise naa mo, lai mo pe o tun si ni ero buruku min in lokan. 

A gbo pe, se ni Paul sa wa sipinle Ogun, to si tedo si Siun, nibi to ti n sise awon to n gbe eru, to tun lawon to maa n ran an lowo. 

Ko pe to di gbajumo nibe lo fi pada lo silu e, to si ji awon omo kekeeke mefa tojo ori won ko ju odun meje si metala.

Won ni se lo n lo awon omo naa nilokulo kulo bii pe won ko niran, bo se n lo won lati se ise alagbafo, bee lo n fi won sise alabaru. 

Nigba towo palaba e maa segi, enikan to mo okan lara awon omo naa nipinle Cross River lo tu asiri e sita, ti won si loo fa a le awon olopaa lowo.

Awon omo naa re e
Paul la gbo pe o bebe pe ki won se oun jeje, to si ni ki won foju aanu wo oun. Sugbon nise lawon eeyan n gbe sepe bo se n soro lojo naa pe o ti fee baye awon omolomo je patapata bi kii ba a se pe asiri e tete tu ni. 

Nigba to n bawon oniroyin soro, Paul so pe iro ni nnkan ti won so nipa oun nitori pe koun too much awon omo naa kuro nilukulu awon loun atawon ebi awon omo naa ti joo towo bowe adehun, tawon si ti joo so asoyepo. 

Ninu oro e, "Nkan ti ko ye awon to mu ejo mi loo sodo awon olopaa nipe mo ti bawon obi awon omo naa soro po. O niye tobi omo kookan n gba lowo mi losoosu. Emi o kii se ajinigbe."

Awon omo naa ni: Promise Augustine, omodun metala, Elijah Emmanuel, omodun meje, Moses Kariel, omodun mejila, Victor Daniel, omodun mejila, Glory Emmanuel, omodun mesan ati Felicia Owu omodun mejila. 

Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu nigba to n soro so pe kawon olopaa to n ri si fifomo seru ati ilokulo tesiwaju ninu iwadii won, Ki won si rii daju pe won foju e bale ejo leyin ti won ba ri okodoro oro.

Bee lo gbawon obi ati alagbato lamoran le ki won rii daju pe won n sabojuto awon omo won daadaa, ki won si rii pe won o kii ran awon omo won nise jade loru. O tun so pe ki won mase bo enu fawon olopaa bi won ba sakiyesi iru awon eeyan bii Paul ladugbo won.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI