Owo olopaa te Joseph to ji omo meji gbe ni Sango - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 30, 2017

Owo olopaa te Joseph to ji omo meji gbe ni Sango

Ibadan lowo olopaa ti te e

Nise lenu ya opo awon eeyan to wa ni oteeli kan taa foruko bo lasiri lagbegbe Ojoo niluu Ibadan lose to koja nigba towo olopaa ipinle Ogun te okunrin kan, Abiodun Joseph, eni odun mejidinlogbon (28), to ji awon omo kekeeke meji gbe.

Nnkan to je koro naa e awon eeyan ni kayeefi lojo naa ni bi won se so pe agbegbe Sango Ota nipinle Ogun ni won so pe Joseph ti ji awon omo naa gbe, to si ko won salo lati fi won gbowo lowo awon obi won.

Gege b'AWIKONKO se gbo, Tobiloba Alesiloye, omodun mejila ati Yusuf Kudus, omodun mejo lawon omo naa ti won so pe lati ojo keedogun osu yi lo ti ji won gbe kuro lodo awon obi won.

Ojule kewaa, agbegbe Cananland, Sango ni won so pe Joseph n gbe, to si n beere egberun lona aadosan (150,000) naira lori omo kan soso, ko to le fi won sile.

AWIKONKO gbo pe ogbon ni Joseph fi tan awon omo naa kuro nile nirole ojo to ko won, ati pe awon omo naa ko tete fura pe ise ibi to fee fi won se niyen.

Won lawon obi awon omo yi lo loo foro naa to awon olopaa Agbara leti pe ki won ma je kina omo jo awon notori teni kan n dunkoko mo awon tawon ko ba tete mu owo wa fi gbawon omo won sile kuro lowo oun.

Latigba naa ni won lawon olopaa ti bere igbese lati ri Joseph mu, sugbon nigba tasiri maa tu lojo Tusde ose to koja yii, se lo so pe ki won wa pade oun loteeli naa.

A gbo pe Joseph ti hale mo awon obi awon omo yi pe boun ba sakiyesi pe won ko olopaa dani, se loun yoo fibon fo ori awon omo naa, sugbon tawon eeyan naa so pe awon ko nii ko olopaa dani nitori temi omo won se pataki sawon ju owo lo.

Nigba ti won so pe Joseph maa jade sita lati loo gba owo to beere, owo olopaa lo jade si, to si bere sii bebe pe ki won se oun jeje, airise se lo so oun deni to n jomo gbe beere owo lowo awon eeyan won.

Agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba soro so pe ojo mejila gbako ni Joseph fi fawon omo naa sahamo lati fi won gba egberun lona oodunrun (300,000) naira lowo awon obi won, sugbon towo awon olopaa te e, tawon omo naa si ti pada sodo awon obi won.

O ni Komisana awon, Ahmed Iliyasu ti tare e si eka ileese won to n ri soro awon ajinigbe lati tubo sewadi e. Bee lo so pe oga awon gbawon obi atawon alagbato lamoran lati tubo maa sabojuto awon won, paapaa bi odun se n pari lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI