Ore meta to n faso soja lu jibiti ti ha - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 8, 2017

Ore meta to n faso soja lu jibiti ti ha

“O pari” loro to jade lenu awon ogbologbo odaran meta ti won ni won n faso soja lu awon eeyan ni jibiti, ti won tun fi n jale niluu Ago-Iwoye ipinle Ogun lojo towo olopaa ipinle Ogun te won.

Ishaera Akan, Nweke Chukwuemeka ati Ibrahim Kato ni won lawon ni ko je kawon araalu, paapaa awon onimoto gbadun alaafia won lati nnkan bi odun meji seyin, sugbon ti owo palaba won segi lose meji seyin.

Ohun taa gbo ni pe, nigba ti ori maa tako won lojo naa, awon kan ti won n ri irin ajo ni won da moto won duro ni nnkan aago mewa aaro ojo naa, ti won si gba orisirisi eru lowo won, ki won too fi won sile.

Awon eeyan naa ni won so pe won gba tesan olopaa lo lati loo fejo sun, nigba tawon olopaa si maa de be, ni won rii pe ooto lawon eeyan naa n so. AWIKONKO gbo pe ibeere tawon olopaa n beere lowo awon odaran meteeta naa ni won ko le dahun daadaa, eyi gan an lo si je ki won fura pe adigunjale ni won.

Nigba ti won lawon odaran fura pe asiri won ti tu ni won gbiyanju lati salo, sugbon towo te meta ninu won, tawon to ku sin a papa bora, sugbon tawon olopaa si n wa won dasiko ta n sakojopo iroyin.

Okan lara awon awako to maa n fi moto sise lati Abeokuta si Ago Iwoye nigba to n jeri soro naa so pe won ti pade ore oun kan ri, ti won si ja a lole. Okunrin naa so pe eru to ba ore oun yen ni ko je ko loo foro naa to awon olopaa leti, o ni igbagbo e ni pe awon olopaa maa gba owo lowo oun.

Bee la tun gbo pe awon eeyan naa tun maa n loo digun jawon eeyan lole nile won loru. Lara awon nnkan ti won ni won ri gba lowo won ni ibon (pump action) kan, ibon kekere (locally made gun) ati aso soja meta ti won wo sorun yi.

Nigba tawon naa n soro, Ibrahim Kato so pe awon kii fi ibon owo won paayan, bo tile je pe awon ma fi n jale. O ni Ishaera lo pe oun pe koun wa maa bawon sise nigba toun ko mo ise toun fe e se mo lati maa fi ri owo ounje.

Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu so pe, loooto loun ti n gbo nipa iroyin awon eeyan yi tipe, sugbon to je pe awon n sise takuntakun lati mu won, to si n ja si pabo. O ni ti kii ba a se awon ti won ja lole to wa foro won to awon olopaa leti ni, o seesee kawon ma tun tii ri won mu.

O wa gbawon araalu lamoran pe ki won rii daju won n ra awon olopaa lowo, nitori pe ko seese ki olopaa wa nibi gbogbo lasiko kan naa, sugbon iroyin ti won ba mu wa fawon lawon maa sise lori e, eyi lo si le fokan awon araalu fiunra won lokan bale, nitori pee mi ati dukia awon araalu lo je awon logun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI