Odaju ni Gomina Amosun je fun wa – Araromi Ajegunle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 18, 2017

Odaju ni Gomina Amosun je fun wa – Araromi Ajegunle

Awon ara ilu Araromi Ajegunle nijoba ibile Sagamu lopopona Ekoo siluu Ibadan ti fi aidunnu won han si Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun latari bo se so won deni ti ko nile lori lasan gangan.

Baale Araromi

Bo tile je pe kii se akoko re e ti won maa f’aidunnu won han, sugbon pelu omije loju lawon eeyan naa fi n baraje soro nile ejo giga kinni to fikale sadugbo Makun, Sagamu lonii ojo Aje, ojo kejidinlogun.

Ohun taa gbo ni pe ijoba ipinle Ogun lo loo wo gbogbo dukia awon eeyan naa lojiji lodun 2013, ti won so gbogbo won deni to n toro je, ti won tun n sun kaakiri ibi tile ba su won sii.

AWIKONKO gbo pe ijoba ko fawon eeyan naa ni gbedeke ojo ti won yoo wa a wole won, ko too di pe won wo ilu naa lati pa gbogbo won lekun, ti won so won si kolobo aye.

Eyi lo fa a, ti won fi pinu lati gbe ijoba ipinle Ogun atawon toro kan bii Physical and Town Planning atawon ileese min in to n ri soro ile ati ile gbigbe labe ijoba ipinle Ogun loo siwaju adajo, iyen Onidajo O. O. Osinuga.

A gbo pe ile ejo tawon eeyan naa gbe ijoba lo, lo mu kijoba tun pada lo lati tun loo tesiwaju ile wiwo lai fu won lara lodun 2015. Opo ile la gbo pe ijoba wo danu.

Lakoko ti igbejo naa n lo lowo, agbejoro fun ilu Araromi Ajegunle, Ogbeni Muyiwa Obaniwa so pe ona aito nijoba ipinle Ogun fi loo wole awon eeyan naa, toun si ni opo awon eri to foju han gbangba. O ni lai pe yi loun tun loo foju oun to awon nnkan to n sele nibe.

O loun ti fi gbogbo nnkan, atawon eri toun ni lowo sowo si agbejoro ijoba, Ogbeni Awofeso, sugbon ti ko foun lesi.

Ogbeni Awofeso nigba toun n soro, o loun ko mo nnkan nipa awon esun ti won fi kan ijoba, ati pe aheso, ati awijare lawon eeyan naa n so lenu lati fi tako ijoba ipinle Ogun, toun si fe ki ile ejo da ejo naa nu.

Adajo naa ni ti e so pe pelu awon eri aridaju toun ti ri yii, toun si ti n bawon ba ejo naa bo lati odun 2013, o fese mule, ati pe ase toun ti pa latodun 2015 pe enikeni, yala, ijoba ipinle Ogun tabi awon araalu ko gbodo de ori ile ti won ti wole lati se ohunkohun nibe titi digba toun yoo fi pari ejo naa, o si sun igbejo min in si ogunjo osu to m bo. 

Nigba to n b’AWIKONKO soro ninu ogba kootu naa, Baale ilu Araromi Ajegunle, Oloye Tajudeen Aina Obe pelu omije loju so pe, “Adajo soro daadaa nitori pe o ri wa, o si mo pe nnkan ti won se fun wa ko bojumu. Nise ni won n gbe awon agbalagba jade ni tipatipa, ti won si n wole lo.

Iya arugbo ti won wole mo lori
“Opo awon eeyan lo je pe ori beedi ni won si wa nigba ti won de laaro ojo naa, elo min in wa to je pe pata lasan lo wa nidi e nigba ti won de, ti won n le won jade. Won ko je kenikeni mu nkankan jade kuro ninu ile won. Won ko ba wa soro kankan rara, o ba wa lojiji, o si ba wa leru, ti ko je ka le mo nnkan taa fee se mo.

“A ti gbe e wa si kootu tele, lo je ko lo agbara buruku e fun wa. Iya agbalagba to je pe lati nnkan bii odun meta lo ti wa ninu ile, toun n saisan, won gbe e jade sita. Iyalenu lo je fun wa. O kan feju mo gbogbo ilu wa kokooko. Ko ye wa rara, nitori pe ilu wa ko bo sori ile ijoba, ti won n pe ni acquisition.

“Mi o riru ijoba Amosun yi ri rara nitori pe gbogbo awon gomina to ti n je ko se nkan bayii ri, ti Amosun yi nikan la ri o. apaayan ni, gbogbo awon eeyan to ti ku bayii lori pe won wole mo won lori. Eru n ba wa gidi. Awon baba to bi baba-baba wa, ibe ni won wa ti won bi iru awa bayii si, iru eleyi ko sele.

“Gomina to je koja, Otunba Gbenga Daniel, o fun wa ni ina, omi atawon nkan amayederun, amosun ko ri nnkan se ju pe ko pa wa lekun, ko le wa danu lo, laarin ilu baba wa.”

Okan lara awon araalu naa, to so pe ile aburo oun ati soobu ewa lara awon ile ti won wo danu, Arabinrin Adebayo so pe yato si pe won wole aburo oun, won tun ba awon tirela to fi n sise je. Ninu oro e, o ni “Ibi taburo mi ni soobu si ko legbe marose, won wobe loo wo soobu e, won tun ba tirela e je.

“O nilu to je pe Oba Ewusi lo fi baale to wa nibe je, tawon eeyan si n taja, ti won n sowo lati rowo mu lo senu. Awon eeyan ku sii leyin ti won wole won tan. Eni to kole de aarin ti ko rowo pari e loo ta moto e lati fi pari e, won tun woo.

“Iya arugbo kan tojo ori e ti le laadorun naa ti laarun ropa rose latari e. won toro je bayii ni. Nigba ti won wa a ba wa pe awon fee di APC, a o mo pe nnkan ti won maa yipada si re e, a o mo pe se ni won maa wa pa wa lekun. Ki gbogbo omo Naijiria gba wa lowo Amosun to n fojoojumo pa wa lekun o. gbogbo wa la dibo fun un nibi to je pe se lo tun wa a doju ija ko wa.”
 
Bakan naa ni Ogbeni Kayode Araoye so pe ile toun loo ya owo ko, to ye koun maa feyinti lati je igbadun, ijoba wo o moun lori. O ni inu gbese loun wa bayii, toun n woju Olorun.

Lati tun ba agbejoro Awofeso soro siwaju sii, se loo so pe ko sibi ti agbejoro ti n boniroyin soro leyin igbejo, ko bofin mu, nitori ni ko saaye lati gboro lenu oun.

Ohun taa gbo bayii ni pe ijoba ipinle Ogun ti n wa ona lati ledi apo po pelu agbejoro awon araalu Araromi, Ogbeni Obaniwa lati fa oju e mora, lati le pana ejo naa, sugbon ti won lokunrin yari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI