Bo tile je
pe ko din ni meje lawon towo olopaa ipinle Ogun ti te lori esun ajagungbale ati
wipe won seku pa oloogbe Mufutau Akinyemi Mobolaji lojo Abameta Satide to lohun
sinu oko e, sine iwadii si n lo lowo.
Gege b’AWIKONKO
se gbo, Mufutau la gbo pe o loo sabewo sinu oko e to wa ni abule kan ti won pe
ni Akasun lagbegbe Ajagboju niluu Ado Odo Ota nipinle Ogun ni nnkan bi aago
mesan aabo aaro ojo naa, ko too di pe awon gendekunrin meji kan loo koluu, ti
won si saa pa sibe.
Ohun taa
gbo ni pe ko too di pe won wonu oko to Mufutau, eni odun merinlelaadota,
orisirisi oro ihale iku ni won ti fi n ranse soun atawon kan Mufutau ti won
loun ni oga ileese Touch of Glass, eka egbe alajeseku Agbe-Lagba.
A gbo pe
ijoba ipinle Ogun ni won ta ile naa fun won lati maa fi sise oko gege bi ipinu
ijoba lati safgbateru ise agbe, ti won si tun ti fun won lase lati sse
ohunkohun to jemoo ise agbe lori e.
Iwadii tun
fi ye wa pe Mufutau atawon meji kan ni won jo wa ninu oko yi lojo naa, sugbon
tawon to ku sa asala femi ara won nigba ti won ri owo tawon odaran ti won so pe
odu ni won lagbegbe naa gbe.
Lesekese
lawon araabule ti loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si bere iwadii lati
mu awon eeyan naa bale. Irole ojo naa ni won sin Mufutau nilana Musulumi.
Ninu
atejise ti Ogbeni Lawon Jagundina ko ranse sijoba ipinle naa lo ti so pe kijoba
tete waa gba awon nitori pe oun ni won so pe iku kan, leyin ti won pa Mufutau
lokan oun atawon eeyan oun ko ti bale mo nitori wahala awon ajagungbale.
Agbenuso
fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe bo tile je pe iwadii si n
lowo, sibe owo ti te awon awon afurasi meje, tawon si ti n foro wa won lenu wo.
O so pe
komisana awon ti pase pe ki eka ileese olopaa SCIID de bere ise iwadii.
No comments:
Post a Comment