Iyalenu loro naa je
lojo Tusde to koja yi nigba ti okan lara awon osise ijoba ipinle Ogun nipa eto
ipawo wole ati okan lara awon to wa ra agbo odun Ileya koju ija sira won nitori
owo ori.
Gege b'AWIKONKO se
gbo, Muhammad Sanusi la gbo pe o lo si Oja Olomore nijoba ibile Abeokuta
North-East ipinle naa lati loo ra agbo Ileya, to je egberun marundinlogoji (₦35,000)
naira.
Sugbon nigba to ra
eran agbo naa tan, ni osise ijoba yi loo ba a pe dandan lo gbodo san owo ori
eran agbo to ra, eedegbeta (₦500)
naira.
Ohun taa gbo ni pe,
se ni Muhammad lanu sile pe igba wo ni sisan owo ori lori oja teeyan ba ra tun
bere nigba ti kii se pe akoko re e toun maa maa ra iru nnkan bee.
A gbo pe Muhammad so
pe oun ko le san owo naa nitori pe ko si ninu iwe ofin lati maa san iru owo
bee, sugbon nkkan taa gno pe osise ijoba naa so pada ni pe dandan ni ko san an
motori pe igbese tintun ti ijoba ibile idagbasoke naa sese sagbekale e ni.
Eyi lo fa a tawon
osise ijoba se pe afi kawon gba eran agno naa sile digba tokunrin naa yoo fi
pada wa a san owo eedegbeta naira naa fun won kawon to yonda e fun un lati maa
muu lo.
Bo se di pe awon
mejeeji gbena woju ara won re e, ti won si fe maa lu ara won ko too di pe awon
toro naa soju e ko si won laarim pe ki won ni suuru funra won.
Nigba to n bakoroyin
wa soro, Muhammad so pe iyalenu loro naa je foun nitori pe oun ko gboru oro bee
ri laye oun, o ni bi eni to fee fowo ola gba oun loju lo ri.
Ninu oro e, o ni "Mi
o lowo kankan lati so, nibo ni won ti n seru e. Ki won gbe mi lo sibikibi, mo
setan lati tele won, koda to ba je ile ejo ni. Mi o gbo ri pe won n san owo ori
lati pa eran ti a ba ra fun Ileya."
Bee ni okan lara
awon toro naa soju e, toun naa wa ra eran, ti ko setan lati daruko e fun wa so
pe ona eburu lawon osise ijobaa naa tu fee gba lati maa fi lu awon araalu ni
jibiti owo, ti won pe ni owo ori.
Nigba toro naa koja
oju tawon eeyan fi pe lo faa tawon oloye oja naa fi sepade pajawiri pelu awon
osise ijoba naa,sugbon leyin ipade la gno pe won ti fi owo naa sinu abadofin
ipawo wole sinu apo ijoba ibile idagbasoke naa.
Nigba to n soro
oludari eka (Veterinary Services) nipinle Ogun, Dokita Dotun Sorunke to lewaju
iko to loo sabewo soja lojo naa nigba to n soro so pe igbese tuntun ni, awon ko
si le yii pada.
Ninu oro e, "A
ri gege bi anfaani lati maa fi ri owo. Ti won kii ba a se be e tele, iyen o
tunmo si pe won tun ni se e nitori pe ofin si wa. Onikaluku lo n wa ona lati fi
pawo wole sapo ara e."
Bakan naa ni olori
oja Olomore, Alaaji Seni Folarin so pe gnogbo igbese lati petu sawon osise
ijobaa naa ninu lo ja si pabo, toun si ri gege bi ona lati le awon onibara
jinna si oja naa.
Bee ni Arabinrin
Kehinde Shodunke to je okan lara awom to n ta eran loja naa fehonu han pe iwa
odaju lawon eeyan naa hu nitori pe owo ti won n gba yen ti poju nnkan tawon
araalu le maa san.
O ni pe eeyan wa ra
eran ko tunmo si pe owo wa lowo won, onikalu lo nibi ti bata ti n ta lese, wipe
eeyan ko owo wa ra eran ko tunmo si pe owo wa lowo won. O lelo min in wa to je
pe o lo ya owo lati wa fi ra eran Ileya ni.
Gbogbo igbese lati
ba alaga ijoba ibile idagbasoke naa soro lo ja si pabo, bee naa ni ako ri
komisana foro ipawo wole sapo ijoba ipinle Ogun soro titi digba ti a fi n sakojopo
iroyin yi.
No comments:
Post a Comment