Ese ko
gbero ni gbongan ayeye igbalode DLK to wa niluu Abeokuta lojo Sande to koja yi
nibi ti okan lara awon gbajumo agba osere to filuu Abeokuta sebugbe Emir Kayode
Akindina ti ayeye ojo ibi aadota odun loke eepe.
Bawon
osere nipinle Ogun se yabo gbongan ayeye naa ti Alaaji Wasiu Alabi Pasuma ti
dalu bole fawon alejo pataki, bee lawon osere lati ipinle Ekoo at’Oyo naa ko
gbeyin lojo naa.
Awon Oba
alaye bii; Alawowo tiluu Awowo; Oba Rasheed Abdulahi Adewale, Olu Iwo tiluu Iwo
ati Eselu tiluu Eselu lo wa lori ijokoo, to fi mo Gomina ipinle Ogun, Ibikunle
Amosun ti akowe ipinle Ogun, Taiwo Adeoluwa soju fun atawon oloselu bii Gboyega
Nasiru Isiaka, GNI; Onarebu Adijat Adeleye.
Lara awon
olorin to tun korin lojo naa ni Alaaji Sefiu Alao, Baba Oko; Beulah; Boye Best
atawon olorin takasufe lorisirisi. Awon maketa bii Tenten Pictures ati Alaaji
Kazeem, iyen Epsalum ko gbeyin, to fi mo MC Oluomo.
Nigba to n
soro, Omoba Dele Odule to je Aare egbe osere TAMPAN, o so pe “Mo ki olojo ibi
oni, Oloye Diakoni Emir Kayode Akindina ku ayeye aadota odun, a a se opolopo e
laye ninu alaafia, owo aiku baale oro. Wiwa sibi mi lonii, ona meji lo pin si.
Akoko ni pe, gege bi osere ti eni to n se ayeye aadota naa je osere, to tun je
ninu egbe kan naa, TAMPAN taa jo wa, eto mi ni lati waa se ojuse mi gege bi
aare. Eleekeji ni pe, oro ti mo fee so yi, e ma binu, e ma rii bi igberaga. Mo
wa gege bii baba osere nipinle Ogun.
“Nigba ti
mo n sayeye ogoji odun ti mo bere ere ori itage, opo awon eeyan ni won n so pe
ko ri bee. Mo so pe ko le ye won, sugbon yoo ye won lola. Osagie wa nibi, igba
ti mo lo sileewe awon olukoni (Teachers’ Training College) to wa ni Oru ni mo
pade Osagie. Sugbon Osagie funra e mo wipe ipile ise tiata ni mo ti n bo.
Bee lo tun
lo anfaani naa lati gboriyin fawon osere tiata nipinle Ogun, o ni “Mo dupe fun
nkankan nipinle Ogun, mo si gbodo f’onte luu. Awon omo ipinle Ogun nikan lo n
se deede, won n sise takuntakun gan an, won n fi gbogbo ara sise gidigidi. Inu
mi dun pe mo je oomo ipinle Ogun, mo si le fowo e soya pe omo ipinle yi ni mi,
nitori pe won n gbiyanju gan an, to ba ti doro ka sise tiata.
“Oro won
kii se ka soju aye, tabi ka ri mi, bi ija ba wa nibe, e je ka mu yen kuro. Won
n sise takun-takun, idi ni yi to fi je pe awon ni won n tayo ju, ko si jo mi
loju. Olorun Olodumare ma ko si ni je ki won wale.”
Lakotan,
Omoba Odule so pe “Nigba ti won mu iwe ipe (invitation card) wa ba mi, mi o ti
e mo pe o ti pe aadota odun, abajo to fi n gbena woju awon booda e, a se oun
naa rii pe oun ti dagba ni, ko le gbena woju mi nitori pe booda ni mi. Aadota
oodun kii sere rara, ki Olorun je ki eni ti ko tii pe aadota odun, ko pe e pelu
alaafia.
“Beeyan ba
pe aadota odun, o ti koko jagunmolu akoko naa, o loju eni to le jagun akoko, ko
wo aadota odun. Amoran mi ni pe ki Kayode loo sinmi naa fungba die bo se pe
aadota odun yi, obi to ba fara sin lo maa n gbo. To ba ti pe odun
mejilelaadota, ko tun bere ise lojuu pereu, titi to maa fi pe odun
mokandinlogota.
“To ba ti
waa pe ogota odun, nnkan to ba fee se, ko tesiwaju, nitori pe orun t’olomo nla
naa la jo n lo.”
Alaaji
Ebun Oloyede, Olaiya Igwe nigba toun naa n soro so pe, “Kayode Akindina to n se
ayeye aadota odun lonii, awon elomin le maa ro pe bo ya ko to bee nitori pe o n
ge irun e lo sile, o tun loju omo kekere, agbalagba arugbo ni. Omo Akindina ti
mo mo ti to ogbon odun tabi ko ju bee lo die, sugbon tori pe won n se ni ‘Sir
Kay’. Bee naa ni Pasuma toun naa fee se ayeye aadota odun bayii, awon eeyan lo
n so pe ko to be. O n dogbon sii ni, o ju bee lo, o n din ojo ori e ku ni,
sugbon tori pe e n pe ni Paso, agbalagba ni.
“E fi temi
sile, awon kan ni mi o to iyen odun ti mo to, o temilorun bee, K1 ni mo fi jo.
Sugbon nigba ti won ba ni ki baba yin wa gba boolu lori fiidi, ti mo ba danu, e
e mo pe mo ti gbo, ko ye opolopo yin ni. Olorun oore ofe lo n funni lebun
beeyan ba se ri. Agbalagba ni wa, eeyan ko kii gbo nidi ise tiata ni, ojoojumo
la n dagba, sugbon e lo ro pe a o to bi a se pe ara wa. Eni to ba fi ojo ori
kun ti e, o n ranse pe saare ti won maa sin in si ni.
“Kayode
Akindina ko gba iranu laaye, o n bowo fagba gidigidi, sugbon ko ni faaye gba
iranu. Ti e ba pe e pe ko waa ba a yin kopa ninu fiimu, ti e si fun un ni ipa
ogun lati ko, to ba ti baa yin se mewaa, adura ni ki e maa gba lati pari eyi to
ku, ki e si tete maa bere laaro tabi losan, nitori pe ko baa yin bo soju kamera
ti aago meje irole ba ti lu.
“Awon omo
Kayode ko nii ji Kayode lai kii se pe o ba ji funra e. O ni ilana ati
ikora-eni-nijanu lori bo se n se nkan e. Kii sin owo, ti o ba lowo, o nii sapo
ara e ni, sugbon o maa pon e le. Aburo mi daadaa ni Kayode Akindina. O kose
tiata lati ibere dopin, o si mo nipa e daadaa. Ninu awon wonran-wonran to maa n
se, eyi to ji lara mi lo po ju nibe, ninu ka kopa, eyi to ji lara mi wa nibe.
“Ju gbogbo
e lo, nnkan ti mo fee so ni pe, nnkan ti onikaluku ba n se, ojo ori e lo
lojoojumo, Olorun a je ka pe laye, a o si nii finira logba. Nitori naa, maa fi
asiko yi ki e kuu oriire pe waa se opolopo odun laye pelu ifokanbale. Bo o se
nirawo yi, ko nii ku, wa a tun rowo fi lo.”
Saaju
akoko yi ni Amofin Taiwo Adeoluwa ti so pe “Mo fee fi tokan-tokan so pe inu mi
dun pe mo wa nibi lati soju oga mi, ati lati soju ara mi. Inu wa maa n dun
nipinle Ogun lati bu ola fun awon to ba je ti wa, eyi ti Mista Paragon je okan
lara won. A wa nibi lati sajoyo pelu eni to ti ko ipa ribiribi, to tun ti ko
awon eeyan lekoo.
“Nitori pe
e je gbajumo, ko je ki e le mo iyi lati maa sajoyo ara yin. Mo maa n so fun
Mista Latin ni gbogbo igba pe eyin diigi (mirror) tawon eeyan to wa nita fi n
wo wa, eyin ni diigi ti a lo anfaani. Nnkan ti eyi elere ba so pe a je naa la
je, nitori e la se maa n wa anfaani lati fi emi imoore wa han pada sii yin.
“Nigba taa
de lodun 2011, awon die ni won gba wa laaye, sugbon fun ifowosopo ati
igbarukuti gbogbo yin, paapaa julo agboole eyin osere tiata, Olorun se iwon to
lee se. Lonii, a wa n dupe lowo Olorun foun to ti se fun wa, a o si le ma fi
emi imoore wa han sii yin.
“Mi o mo
pe omo kekere gan an ni Emir, Mista Paragon niori pe awon fiimu yin ti poju
iyen ojo ori yin lo. Nigba ti e wa pe e fee sayeye aadota odun, mo ni mi o ti e
mo pe omo kekere lawon eeyan yi sa. Eku oriire nla. Mo maa n fi yin yangan,
ipinle Ogun naa si n fi yin yangan. Boya e fe tabi e ko, e pelu awon to n gbe
ogo ipinle Ogun soke.”
Nigba toun
naa soro, olojo ibi funra e, Kayode Akindina so pe ko si nkan meji toun fee so
ju pe koun dupe lowo Olorun lo, nitori pe opo ojo loti ro, opo iji lo si ti ja,
sugbon ti Olorun moun bori e.
O wa dupe
lowo awon alejo atawon to sagbateru ayeye naa pe ko le lo bawon se lero.
Lara awon
osere to tun wa nibe lojo naa ni Omoba Dele Odule; Otunba Bolaji Amusan, Mr
Latin; Omoba Yomi Osagie; Omoba Surajudeen Adewunmi Dagilapa, alagba egbe
TAMPAN; Saheed Balogun; Faithia Balogun; Odunlade Adekola; Alaaji Waheed
Ijaduade, Dimeji; Akeem Alamutu, Eba; Yinka Adebanjo; Baba Super; Ganiyu
Edunjobi; Monsuru Ijayegbemi; YS Kareem; Yemi Adegunju; Afeez Owo Abiodun;
Muyiwa Ademola; Toyosi Adesanya; Olaniyi Afonja, Sanyeri; Segun Ogungbe; Eniola
Ajao atawon min in.
No comments:
Post a Comment