Eyi ni bi FUNAAB se yan giwa tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 19, 2017

Eyi ni bi FUNAAB se yan giwa tuntun

Idunnu lo subu lu gbogbo awon oga agba, awon alakoso, gbogbo osise, to fi mo awon akekoo patapata nileewe fasiti ise ogbin, iyen Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB) lojo Aje Monde ana, nigba ti won kede Ojogbon Felix Kolawole Salako gege bii giwa tuntun ti yoo maa sakoso ileewe naa.

Ojogbon Felix Kolawole, giwa tuntun
Be o ba gbagbe, ojo Isegun Tusde, ojo kerinlelogun osu karun ni saa isakoso giwa ana, Ojogbon Olusola Oyewole dopin, ti won si yan Ojogbon Enikuomehin l’Ojoru Wesde, ojo karundinlogbon lati je gege bii adele ti yoo maa tesiwaju digba ti won yoo fi pinu lati yan giwa min in.

Ninu atejade ti Arabinrin Emi’ Alawode to je agbenuso fun ileewe naa fi sowo s’AWIKONKO laaro oni Tusde, o je ko ye wa pe ipinu lati yan Ojogbon Felix Salako ko seyin eni to je giwa agba patapata ati alaga isakoso ileewe naa (Pro-Chancellor and Chairman of the Council), Dokita Aboki Zawha.

Ohun taa gbo ni pe, bi won se yan Ojogbon Salako gege bii giwa tuntun, bee naa ni won yan Dokita Hakeem Adekola gege bii olugbaniwole (Registrar) ati Ogbeni Chukwunwike Ezekpeazu gege bii Bursar.

AWIKONKO gbo pe yiyan ti won yan awon eeyan naa lati fi ropo awon aaye to meta to sofo yi lo ni ibamu pelu ofin ati ilana ti won fi da ileewe naa sile.

Ninu oro Dokita Zawha lo ti so pe latigba ti saa isakoso giwa ana, Ojogbon Oyewole ti tan, tawon si yan adele giwa lawon ti bere igbese lati yan giwa min in, tawon si gbe ipolowo jade sita fawon to ba nife sawon ipo naa.

O so pe leyin topo awon eeyan fiwe ranse sawon, tawon si se ayewo fun gbogbo won pata, lo je kawon pinu lati mu awon to yege ninu ayewo (screening) naa.

Giwa tuntun naa, Ojogbon Salako to je omo bibi ipinle ilu Ibadan nipinle Oyo, ti won bi lodun 1961 la gbo pe o darapo mo ileewe naa lodun 2000 pelu ipo oluko agba, to si sakitiyan lati di ojogbon lodun 2006.

Koleeji Igbobi nipinle Eko lo lo, ko too tesiwaju lo si ileewe University of Nigeria, Nsukka nibi to ti ni B.A Agric (Hons) ati M.Sc degree nipa ekoo Soil Science lodun 1983 1ti 1986.

Odun 1997 lo gboye Ph.D ni fasiti Ibadan (UI). Bakan naa lo tun je Ojogbon Soil Physics leka Soil and Land Management.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI