Iwa ajebanu lo fa oro awon agbodegba taa ni lorileede yi – VIO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 23, 2017

Iwa ajebanu lo fa oro awon agbodegba taa ni lorileede yi – VIO

Oga agba ajo to n ri si sisabojuto iwe irinna awon awako loju popo, iyen ajo Vehicle Inspection Office, VIO nipinle Ogun, Onimo-ero Ademeyin Olugboyega Adewale ti so pe ko si nnkan meji to fa oro awon agbodegba to n sakoba fun pipawo sapo ijoba lona to to, bi ko se ti iwa ajebanu to n ti wo wa lewu lo.

Taofeek Babalola, agbenuso VIO
Onimo-ero Ademeyin soro yi lakoko to n b’AWIKONKO soro lojo Eti Fraide to koja yi nibi idanilekoo ti ajo naa se fawon fegbe awon oludasile ileewe bi a ti n ko nipa oko wiwa, iyen Driving Schools proprietors, eka tipinle Ogun, to waye ninu gbongan to wa ninu ogba ajo naa lagbegbe Kotopo, Abeokuta.

O niwa ainitelorun lo si n fa tawon eeyan, paapaa awon osise ijoba fi n lo gba ona eyin ja ijoba lole, ati pe eni towo palabba e ba ti segi, dandan ni ko foju bale ejo lati gba idajo to to sii.

Nigba to n soro nipa idi pataki ti won fi gbe idanilekoo naa kale, o so pe kawon tubo le gbogun ti ayederu iwe irinna loju popona lo mu kawon gbe idanilekoo yi kale fawon egbe yi nitori pe awon naa tun n ran won lowo lati bawon eeyan soro, paapaa awon to ba sese bere wiwa loju popona soro nipa ona ti won le to lati gba iwe irinna to ye, ati bi won se le maa wa owo loju popona, ti ko fi ni si ijamba.

O wa gbawon awako lamoran pe ko nii se iye odun ti won ti n wa oko, ati pe ko nii se pelu iru eeyan ti won je, ki won rii daju pe won n se ohungbogbo lona to ye, to si bofin, ki alaafia le tubo joba.

Nigba to n soro, Komisana foro ise atidagbsoke, Lekan Adegbite ti Ogbeni M.A. Adebiyi soju fun so pe bi ijoba se n gbogun ti iwa ibaje loju popo, ti won si n ri daju pe ipinle Ogun ni awon ona to dun n wo loju, ti moto le rin lai kose, bee naa lawon ajo VIO ko dawo duro lati gbe ise naa yo sita.

Lara awon to wa nibe ni Majisireeti Odeda, Ogbeni Sobayo Ilo; SP Durojaiye toun soju DPO Obantoko; Arabinrin Morolake Filani, to soju ajo TRACE ati Ogbeni Ayemoniase Femi  toun soju OC Oladele ti ajo FRSC.

Agbenuso ajo VIO, Ogbeni Taofeek Abimbola Babalola so pe “Gege bi ofin, ajo VIO nijoba fowo si pe ki won maa fawon to ba fee da ileewe ti won ti n ko nipa oko wiwa sile niwe eri, ti a ba si n se eyi, a ni lati maa bojuto akitiyan lore-koore, eyi lo bi idanilekoo, ki ise ti won n se le je eyi to muna doko, ati pe ki ajosepo to wa laarin won tubo le dan monran sii.”

Abimbola so pe ko tun si ipenija min in tawon n koju ninu ajo naa bi ko se tawon agbodegba to n gbe iwe irinna jade lona aito, tiwo palaba won ba si ti segi, ko si nnkan meji tawon maa se ju kawon gbe won lo sile ejo lo, ki adajo si se ohun to ba ye, nitori pe ohun gbogbo lo ni ofin ti e.

Onimo-ero Sonola nigba toun dawon eeyan lekoo lori koko pataki to pe ni “Ipa tawon ileewe oko wiwa n ko nipa gbigba iwe irinna” so pe oun ri awon oga agba ileewe oko wiwa naa gege bi pataki lawujo latari ipa ti won n ko lati dekun ijamba oju popona.”

Bee naa ni Bayo Otuyemi toun dawon eeyan lekoo leekeeji so pe o se pataki kawon to ba sese fee bere sii wa oko loju popona lati mo nipa ofin ati ilana to de wiwa oko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI