Alaaji Taofeek Adio
Adeyinka to je gomina egbe olorin Fuji, iyen Fuji Musicians Association of Nigeria (FUMAN) nipinle Ogun ti so pe ise
orin Fuji kiko ti yato si oju tawon eeyan fi n wo o, nitori pe gbogbo nkan lo
ti yi pada latari olaju to wole de.
Alaaji Adeyinka soro
yi nibi ayeye ibura fawon oloye egbe tuntun nijoba ibile Abeokuta North lose to
koja ladugbo Ago-Odo, Abeokuta. Nibi to ti so pe o ye kawon maa dan opolo awon
omo egbe won wo leekookan lati le mo eni to dangajia lati korin Fuji ninu won,
to mu ki won da eto kan ti won pe ni FUMAN with
Friends sile.
O ni kii se pe awon
deede pinu lati da eto naa sile, bi ko se lati maa gbe awon omo egbe olorin
Fuji nipinle naa goke agba, kawon naa si le tete dolokiki nitori pe opo ninu
won ni won lebun orin kiko, sugbon to je pe ko si an faani fun won lati korin
fawon eeyan, depodepo pe won a se awo orin jade sita.
Nigba to n soro, o
so pe “Idi pataki taa fi bere eto yi, nitori pe akoko iru e re e lorileede
Naijiria ni pe, a fe e maa mo eni to ye lati gbe laruge nidi ise orin Fuji taa
yan laayo. Kaakiri gbogbo ijoba ibile la si ti ma maa se, to je pe a ma maa
fiwe pe awon eeyan lati waa woran wa.
“Nise la fee se e
gege bii idije laarin awon omo egbe wa, ti a ba ti pari e, a maa ko oruko awon
to ba gbegba oroke sile, leyin naa la maa wo yara igbohun sile lati sise papo
gbe awo orin jade fun won.
“Ko se ni to se tan
lasiko ta a wa yii lati gbe enikan jade faraye, onikaluku maa ja fori ara e ni,
Pasuma ko le gbeeyan jade, bee naa ni Saheed Osupa tabi Malaika. A gbodo ja
fori ara wa ni.”
O wa lo akoko naa
lati gbawon oloye tuntun egbe naa nijoba ibile Abeokuta North lamoran pe ki won
rii daju pe won n wa alaafia ati isokan ninu egbe naa lasiko ti won yoo lo.
Awon omo egbe tuntun
naa ni Ogbeni Fatai Arowora, alaga; Ogbeni Ibrahim Adeyemi, igbakeji alaga
kinni; Arabinrin iyabode Asabi, igbakeji alaga keji; Ogbeni Sulaiman Aremu,
akowe; Ogbeni Moshood Ololade, akapo; Ogbeni Adeboye Ajani, akowe owo; Ogbeni
Kabiru Akanni, alabojuto egbe; Waheed Alamu, Provost ati Olawale Ajao toun je Organizing Secretary.
Bakan naa ni won tun
lo anfaani ojo naa lati fi si akanti ile ifowopamo fawon omo egbe naa kaakiri
ipinle Ogun, eyi ti yoo mu kawon eeyan tete maa dawon mo nigboro peluu kaadi idanimo
(ID Card) ti banki naa fee pese fun won.
Alaaji Adeyinka tun
so siwaju pe ayipada to ti pada sinu egbe latigba toun ti depo naa ko se e ka
tan, lara e ni ti igbese sisi akanti ile ifowopamo, eyi ti ko seyin ti ipenija
tawon ni lati ko awon omo egbe kaakiri orileede Naijiria papo soju kan, iyen Data Base
tawon ko tii ri se.
Alaga tuntun, Ogbeni
Famous Fatai Okiki Arowora topo mon si Mista Packaging so pe “Egbe yi ti wa
tipe, o si maa je nkan to maa dun mo wa ninu ti idagbasoke ba n de ba egbe yi
peluu igbiyanju wa, bo tile je pe a o le ka a tan. A o fe iwa jatijati ninu ise
Fuji mo.
“Ni ijoba ibile
temi, mo n gbiyanju lati fo idoti yen mo, nitori awon eeyab gba pe awon janduku
lo n korin Fuji, ti ko si ye ko ri be. Ko seni ti kii korin Fuji, bawon
Kristeni se n ko o, bee naa lawon Musulumi n ko o, bakan naa lawon esin abalaye
naa n ko o.
“Sugbon o wopo ninu
Musulumi ni won se ro pe awon nikan ni, gbogbo eya lo n ko o, ebun lo si je
feni t’Olorun ba fun lebun e lat ko o. Laye atijo ni won n fenu idoti ko Fuji,
igba ti yi pada to je pe awon to n kekoo jade nileewe giga ti n ko o. Opo awon
ti won n niwe eri tele ti lo n kawe sii.
O wa dupe lowo awon
omo egbe paapaa gomina won fun iggbarukuti won lati je ki ayeye naa wa si
imuse. O si seleri pe oun yoo sa gbogbo agbara oun lati je kawon omo egbe to si
sako lo pada sinu egbe.
No comments:
Post a Comment