Gbogbo obi
to ba n ran omo won lo sileewe giga lo maa n gbadura pe ki lo layo, ki won bo
layo, kawon si le jeun omo, sugbon oro naa ko ri bee nigba tawon akekoo meta
nileewe olukoni, iyen Federal College of Education, to wa nilu Osiele, Abeokuta
fo sanle to si ku lojiji laarin ojo meta.
Bukola |
Titi di bi
a ti n sakojopo iroyin yi ni gbogbo awon akekoo atwon olukoo FCE fi wa ninu
iberubojo, ti won n beere lowo ara won pe taniku kan. Bawon kan se n so pe oro
naa kii soju lasan bee lawon min in so pe ko je tuntun.
Bo tile je
pe orisirisi aheso la gbo pe o fa iku awon omo ti won lojo ori won ko tii ju
odun mejilelogun lo, eka ikekoo Primary Education (PED) lawon meteeta wa.
Oluyemi Bukola ati abioye Rilwan ni won so pe ipile kinni ni won wa, nigba ti
eni kan to ku ti a ko tii mo oruko titi dasiko ti a fi sakojopo iroyin yi tan wa.
Gege b’AWIKONKO
se gbo, won lojo Wesde to koja lo lohun ni Abioye Rilwan deede bere aisan
lakoko to n sedanwo lowo, nibe ni won ti sare gbee lo sileewosan to wa ninu
ogba ileeko naa, sugbon ti won so pe aisan iba lasan lo n se e. Ojo keji ni won
so fun un pe ko tete maa lo sile lati tubo lo gba itoju si lodo awon obi e.
Nigba to
di ojo Tusde to koja la gbo pe Rilwan tun pada se idanwo e, ko too tun pada lo
sile, sugbon nigba to ya ni won so pe aago e ko lo mo. Eyi lo mu kawon akekoo
egbe se pinu lati lo woo nile losan ojo Fraide to koja, sugbon iyalenu lo je
nigba ti won dele won, to je pe isinku e ni won ba.
Oluyemi
Bukola ti won jo wa ninu kilaasi kan naa la gbo pe ojo Aje Monde ni won loo
bere aisan opolo nigba to lo ki ore e to n gbe ninu hostel, ti won si sare gbe
e lo sileewosan to wa ninu ogba, nibe ni won ti so pe ki won tete maa gbe e lo
si Aro nitori toro e ti koja nnkan tawon le dawo le.
Sugbon
nigba to maa di aaro ojo Wesde la gbo pe Bukola ti dagbere faye, eyi to ko
iberubojo sokan gbogbo okan awon akekoo patapata, ti won si tete bere sii pe
awon obi won pe ki won kun fadura lori won.
Boluwatife
toun mo Bukola so pe “Nigba ti aarun alaganna wo o lara, ti won gbe e de
medical, won ni ki won maa gbe e lo si Aro, sugbon nigba ti won pe baba e, o so
pe ki won maa gbe e bo nile foun. Iroyin iku e la gbo losan ojo Wesde.”
Ridwan |
Akekoo
keta ti won so pe ipele keji (200level) loun wa, sugbon ti a ko tii gbo oruko
titi dasiko taa fi sakojopo iroyin yi tan la gbo pe o subu lule lenu geeti to
wonu ogba ile eko naa, nigba tawon akekoo egbe e atawon sikioriti maa fi debi
towa lati ran an lowo dide, o ti ku.
Nigba to n
bakoroyin wa soro nirole ojo Fraide, odomokunrin kan toruko e je odomokunrin kan toun
ati Bukola peluu Rilwan jo wa ninu kilaasi kan naa so pe gege bii ipo toun di
mu ninu kilaasi, oun gbe igbimo kan dide lati loo wo Rilwan nile, sugbon nigba
ti won de be, ni won gbo pe o ti ku, ati pe ko pe ti won sinku e tan ni won de
be.
O so pe ko seni to le ro iku sawon mejeeji nitori pe won kii soro, won ko si ni
ore kankan, ati pe jeje ni won n lo, won kii baayan sere, ayafi to ba wu won
lati rerin ni won maa rerin.
O niyalenu
niku awon akekoo naa je foun atawon elegbe oun toku, ati pe ironu ale kandu,
iyen candle night tawon fee se fun Bukola lo wa lokan awon ko too di pe awon
tun gbo iroyin iku Rilwan.
Akekoo kan
so pe “Idanwo Agric la n se lowo ko too dide, sokoto to wo n jabo tawon eeyan n
wo pe ara ko tii ya daadaa. Lesekese ni won ti sare gbe e lo si medical. Nigba
ti mo maa gbo, won loo ti ku.”
Okan lara
awon akekoo FCE toun wa nipele keta (300level) to b’AWIKONKO soro, to ni ka
foruko boun lasiri so pe bo tile je pe odoodun lawon akekoo ati oluko maa n fo
sanle ku, sugbon bawon eeyan se ku lodun yi je kayeefi, to si n ko eru sokan
awon.
Odomobinrin
naa so pe ko din ni oluko marun to ti ku lodun yi, nigba tawon akekoo ko see ka
tan. O ni nnkan to n ya oun lenu ju ni bo se je pe awon akekoo to wa leka
ikekoo Primary Education (PED) niku naa wopo laarin won.
Bakan naa
ni akekoo min in, toun naa wa ni PED so pe boun ba fi le pari idanwo tawon n se
lowo yi, oun yoo yi eko toun ko pada nitori pe bawon akekoo elegbe oun se n ku
leka ikekoo toun wa ti po ju, eru si n ba oun pupo.
Gbogbo
igbiyanju lati gboro lenu alukoro ileewe naa lo ja si pabo titi dasiko taa fi
sakojopo iryin yi tan.
Ni bayii
ohun taa gbo ni pe inu awon akekoo kan ko dun si aare egbe awon akekoo SUG lori
bo se yari pe won ko le lo moto egbe lati loo fi ki awon obi awon akekoo to fo
sanle ku yi, a gbo pe aare won so pe ki won loo mu eri aridaju iku awon akekoo
naa wa koun to le gba won laaye, sugbon tawon so pe ko sibi tawon ti fe e rii.
No comments:
Post a Comment