Titi di bi a ti n
sakojopo iroyin lawon olopaa ipinle Ogun si fi n wa Kazeem tawon eeyan tun mo
si “Down-jia” ati Mopo ti won pa Yinka Adewoyin, eni odun mokanlelogbon lose to
koja ladugbo Vitalink Campus, Agosi Ifo nipinle Ogun
Yinka nigba to wa laye |
Gege b’AWIKONKO se gbo,
ni nnkan bi aago meji aabo osan ojo Isegun Tusde to koja la gbo pe ile oti ni
Down-jia atawon ore e ti kuro, ti won si gba adugbo naa koja, nibe lo ti ri
baba agbalagba mekaniiki kan to n sise lara tipa ti won paaki siwaju ita soobu
Yinka, to si bere sii fa wahala.
Down-jia ti won nise
panel-beater lo n se la gbo pe okan lara awon oloye nilu Ifo ni mama to bii
lomo, bo tile je pe a ko ri mama e ba soro titi dasiko taa fi sakojopo iroyin
yi tan.
Ohun ta a gbo ni pe won
loo so fun baba naa pe oju titi lo paaki moto si, ko gbe e kuro, baba yi lo so
fun Down-jia pe tipa naa ko si loju titi, ati pe oun ko loun nii, oun kan n
sise lara e ni, lo ba bere sii da ese bo baba agbalagba naa.
A gbo pe aanu gbogbo bi
Down-jia se n gba baba agbalagba kan, Mukaila Laisisi lese lo se Yinka to si n
bee Down-jia pe ko fi sile, sugbon won nise lokunrin naa atawon ore e tun koju
ija Yinka, ti won si luu titi to fi fori gbale, to si daku.
Oku Yinka |
Leseke ti won rii pe
Yinka ti dake, la gbo pe won ti na papa bora. Nibe lawon eeyan ti raaye pe bo
o, ti won sare gbe e lo si osibitu, nibi ti won so pe won ti ko o pe oku eeyan
ni won gbe wa fawon, ko too di pe won gbe e lo si osibitu kan to wa lagbegbe
Banki n’Ifo.
AWIKONKO gbo pe ese kan
aye ese kan orun ni Yinka ti won tun un pe ni Baba Praise wa, ti ko lee se
ohunkohun titi to fi gbemi min in leyin ojo keta.
Baba agbalagba ti won lu
lojo naa, Mukaila Lasisi so pe “Ibi ti mo ti n se moto ni mo wa, to fi de, moto
kan fe e koja niwaju, mo wa so fun un pe ko se suuru, pe aye wa to le gba koja,
sugbon epe lo mu bo enu, awon eeyan lo so fun un pe se ko mo pe agbalagba lawon
to n sepe fun.
“Boun atawon ore e se lo
paaki moto won siwaju lohun ni yen, ti won bo sile pelu irin lowo, ti won lo fi
n na awon eeyan. Igba ti mo rii be e ni mo sare loo ba won pe ki won se jeje,
ni won ba tun koju ija si mi. Igba ti Yinka naa tun de, won tun koju ija sii.
Lasisi ti Yinka fee gba sile |
“Oro naa le debi pe won
fun Yinka lese laya, o si fi ipako lule, lesekese lo ti daku. Bi won se rii pe
o ti daku, ni won ba salo pelu moto won. mo ba sare gbe e lo si osibitu pelu
okada, igba tawon eeyan de ni mo ba lo foro yi to awon olopaa Ifo leti, won fun
mi ni IPO kan pe ka lo mu Down-jia wa.
“Igba taa de soobu e, a o
ba, won lo o ti lo si Kaduna lo ra moto lati bii ojo marun seyin. Sugbon a so
fun won pe oun lo wa se awon eeyan lese lai pe yi. Bo se di pe won pe e lori
aago lati beere ibi to wa, o so fun won pe Ifo loun wa, oun sese de lati Kaduna
ni. Won so fun pe ko maa bo lati wa yanju wahala to da sile, sugbon ti ko
dahun. Titi dasiko yi lao tii ri Down-jia. Sugbon aaro ojo Tosde lo ku, a si ti
gbe e lo si mosuari.”
Michael to ladugbo Temidire
loun ti n sise agerun so pe boun se n bo loun rii pe won n ba Yinka fa wahala,
nigba to si je pe eni to nife awon eeyan pupo ni tawon si jo maa n sere loun ba
loo ba won pe ki won fi sile, o lesekese ni won ti gba oun lese, ti won si bere
sii le oun kaakiri irin lowo.
Okan lara awon ti Yinka
ti ko nise ri, Adegoke Oluwatosin so pe oni suuru ni Yinka, ko si ba eeyan ja
ri latigba toun ti de odo e, ko too di pe oun se firidoomu. O loun ko si nile
lasiko naa, ori foonu ni won ti pe oun.
Mariam, iyawo Yinka |
Iyawo Yinka, Arabinrin
Mariam Adewoyin nigba to n b’AWIKONKO soro pelu omije loju so pe “Ori ijokoo ni
mo fi oko mi sile sii, mo loo mu omo wa nileewe ni. Igba ti mo maa pada de, mo
ba ero repete niwaju ita, mo beere pe ki lo sele, won ni won ti gbe oko mi lo
si osibitu nitori pe awon kan lo luu mo inu soobu.
“Ipo to wa nigba ti mo de
be ko da rara, nitori pe oko ko da mi mo mo, ko pe lawon osise osibitu so pe
agbara awon ko gbe e mo, ka gbe e lo sibo min in, a wa pinu la ti gbe e lo si
osibitu kan to wa ladugbo Olomu, nitosi Banki, Ifo. Ojo keta lo dake laaro ojo
Tosde.
Iya e, Arabinrin Bukola
Awoyemi nigba to n soro so pe “ipade egbe alajeseku ni mo wa ti won ti ranse pe
mi pe won ti lu Yinka daku, won si ti gbe e lo si osibitu. Igba ti mo dele ni
mo so fawon eeyan pe ki won mu mi de be.
“Tipa kan to je ti baba
iyawo e, ti won paaki siwaju ita ile won ni won so pe eni kan to n je Down-jia
so pe oju ona lo wa, omose baba iyawo lo n tun tipa yen se lowo tawon Down-jia
fi debe ni won fi bere wahala pelu won, ko too di pe won ti omo mi subu.”
Bukola, Iya Yinka |
Eni to je gege bii baba
e, Komureedi Awoyemi Oladosu, eni to so pe odun mewaa ni Yinka wa toun ti fe
iya e so pe ibise loun ti n bo ki won too so foun pe Yinka ti wa losibitu.
Agbenuso ileese olopaa ipinle Ogun,
Ogbeni Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri sisele naa so pe looto, o lesekese
tawon ti gbo ni won ti lo sibe, ti won si peluu gbe Yinka lo sileewosan.
O lojo keji ni won gbo pe o ti dagbere
faye, iyen laaro Tosde, ati pe iwadii si n lo lowo nitori pe o ti do esun
apaayan, tawon si gbodo rowo to Awon odaran naa lati foro wa won lenu wo. O
loun yoo fi ababo to wa leti towo Awon ba ti te won.
No comments:
Post a Comment