Ileewe
giga fasiti to n kekoo nipa ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta,
FUNAAB ti bere iforukosile igbaniwole fawon akekoo tuntun fun saa ikekoo odun
2017/2018.
Gege
bi atejade ti olugbaniwole agba, Dokita Arabinrin L.O. Onwuka fi sowo s'AWIKONKO lojo Tosde to koja yi, o ni awon nipele 100level, 200level ati
300level laaye si sile fun lati foruko sile lori ero ayelujara won http://admission.unaab.edu.ng.
Dokita
Onwuka lawon to kopa ninu idanwo UTME to koja yi, ti won si ni ogosan (180)
maaki, o kere ju, iyen fawon to ba fee kekoo nipa ogbin ati igba maaki
fawon to ba fee kekoo nipa imo ero (Engineering, Sciences and Veterinary
programmes) nikan lo lanfaani lati fi gbogbo oro nipa won (Bio Data) sile ki
asiko too lo.
Ojoru
Wesde, ojo kefa osu yi ni eto naa bere, ti yoo si pari lojo kokanlelogun osu
yi, sugbon aaye si si sile fawon to ba fee wole si ipele 200level ati 300level
titi di ogbon ojo osu to m bo.
Be
o ba gbagbe, ose to koja ni won fi igbelewon igbaniwole fun saa ikekoo odun yi,
2017/2018 sita fawon akekoo tuntun to ba fee wole sileeko naa.
Gege bi
atejade ti igbimo idagbasoke ileeko naa fi sita laaro oni, eyi ti eda e te
AWIKONKO lowo je ko ye wa pe ki igbaniwole saa ikekoo tuntun yi le lo bo se ye,
awon ni lati tete fi sita fawon eeyan lati tete mo ipinu won paapaa awon to mu
FUNAAB gege bi akoko ninu idanwo Jamb to waye laipe yi.
Ipinu yi
la gbo pe o waye leyin abajade ipade to waye laarin awon alase ileewe naa ati
Minisita foro ekoo lorileede Naijiria.
Ohun taa
gbo ni pe ipele meji ni eto igbelewon igbaniwole naa wa, eyi to je pe maaki
ogun din ni igba (180) ni ipele akoko, nigba ti igba maaki (200) je ipele keji.
No comments:
Post a Comment