Titi di bi e ti n ka iroyin yi
lowo lawon molebi okunrin kan, Buraimoh Oludare to pokunso sinu yara e lojo Aje
Monde ose to koja si fi wa ninu ibanuje okan, nitori ti won so pe oloogbe naa
ko fu won lara, tabi ko sebi eni pe oro kan n gbe lokan, ko too pinu lati gbemi
ara e.
Boro naa se n se awon ebi Oludare
ni kayeefi, bee lo tun n je iyalenu fawon to wa nibi isele naa, ti won n so
orisiri nnkan to le fa a lati pokunso. Bawon se n so pe kii soju lasan, o lowo
aye ninu, bee lawon kan n so pe boya ile aye lo suu ni.
Oludare, ti won loun ni oludare
leka ileese to n soro awon odo nipinle Ekoo ni won ni ko ju nnkan bi iseju
meedogun lo to fun okan lara awon omo e, Dotun to ni aisan iba loogun, ko too
wo yara e lo lati loo pokunso.
Phase ii, Unity Estate ladugbo
Gbonagun, Obantoko, Aebokuta nisele buruku naa ti waye ni nnkan bii aago merin
irole, to si gba omije loju opo awon to wa nibe lojo naa, nitori ti won so pe
okunrin naa ko eeyan mora, o si maa n bawon eeyan sere.
Dotun to loun ati baba oun lawon
jo wa ninu ile lojo naa, ko si pe ti baba oun foun loogun nitori ara oun ti ko
ya, toun ni aisan iba lo gba yara e lo, toun ti e ro pe nise lo fee lo sun, lai
mo pe ero buruku naa ti wa lokan e.
Omo naa so pe nigba toun ko tete
gbo ohun baba oun, loun pe e wo, ti ko si da oun lohun, lo je koun loo yoju wo
ninu yara lati mo nnkan to n se nibe, sugbon iyalenu lo je nigba toun ri loke
faanu, nibi to ti n min jolojolo nibi to so ara e ko sii pelu aso oke.
O loun ko mo nnkan toun le se
nitori ti aya oun ja ati pe oun ko ri iru nnkan bee ri laye oun, lo je koun sa
jade sita lati loo pe awon araadugbo pe ki won wa gba oun.
Nigba to n soro pelu ibanuje
okan, iyawo oloogbe naa so pe oun ko si nile lasiko tisele naa waye, awon
araadugbo lo pe oun lati so nnkan to sele, toun si gbera lesekese kuro nibi
toun wa lati maa bo nile.
Obinrin naa so pe iwa odaju loko
oun hu nitori pe asiko to ye kawon maa gbadun lo gbemi ara e, ati pe ko ba oun
soro pe bioya oro kan n gbe e lokan, koun si gba a nimoran.
Lara awon araadugbo naa to
bakoroyin wa soro lojo Wesde so pe o seese ko je lati ibi ise ni won ti saa si
okunrin naa, ati pe lopo igba lawon osise ijoba maa saa si ara won, ti won si
maa je ara won lese.
Eni naa to ni ka foruko boun
lasiri so pe nigba toro naa sele, awon agbaagba to wa nitosi ni won ranse sawon
olopaa Obantoko lati waa foju won to isele naa, ti won si gbe oku e lo si
motuari jenera to wa n’Ijaye.
No comments:
Post a Comment