Eyi ni bi Ferisope se ku sinu aisan okan to n se e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 30, 2017

Eyi ni bi Ferisope se ku sinu aisan okan to n se e

Bo tile je pe kii se idunnu ebi atawon to sunmo ebi omobinrin tojo ori e ko tii ju odun mokanlelogun lo, to doloogbe lai pe yi, Ologun Ferisope Love ladugbo Ayandeji, Ositelu, Sango ipinle Ogun, sugbon isele naa to eyi ti won fi n kekoo.


Ohun taa gbo ni pe aisan okan (kidney) ni won so pe o seku pa Ferisope ti won so pe okan lara awon oluso aguntan ninu ijo Deeper Life ni baba e.

AWIKONKO gbo pe o ti pe tomobinrin naa ti ni aisan yi, sugbon to je pe adura loun atawon obi e fi n gbe e pe ki Olorun ba won mu aisan naa kuro nitori igbagbo ti won ni.

Gege bi eni to sunmo Ferisope se so nigba to n b'AWIKONKO soro lojo Wesde ose to koja, o ni laipe yi ni won da Ferisope duro sileewosan kan ti ko daruko e, nibi ti won so pe ise abe ni won maa se fun.

Eni naa to ni ka foruko boun lasiri so pe bo tile je pe Ferisope atawon obi e ko koko gba lati lo sileewosan sugbon nigba ti inira naa po fun, ni won too gbe e lo, to si lo bi ojo meloo kan.

Ohun taa gbo ni pe agbejoro to ri jaje ni baba e tele ko to o di pe nnkan denu kole fun lojiji, iya e la gbo pe o mojuto ileese omi (pure water factory) taa foruko bo lasiri ti won dasile ladugbo Ositelu, Abebi nitosi ile won.

Gbogbo bi won se so pe awon eeyan n gba oun atawon obi e lamoran pe ki won gba lati sise abe fun un ni won so pe won yari nitori tawon nigbagbo ninu Olorun tawon n sin, ati pe iwosan atoke wa lo se pataki.

Ferisope lakoko tawon ore e lo wo nile
Eyi gan an ni won so pe o gbe Ferisope kuro losibitu lojo Tusde ose to lo lohun, iyen ojo kokandinlogun, to si dele. A gbo pe bawon ore e ti won ni won ti n gbadura fun tele se gbo pe o ti dele ni won tun loo kii.

Iyalenu lo je nigba to maa di aaro ojo Wesde to tele, to je pe iroyin iku e lo gba gbogbo adugbo won kan, ti okan lara awon ore e tun gbe iroyin iku e sori ero ayelujara facebook.

Won ni loru moju ni kini naa yiwo mo o lowo, to si je irora to po ki akuko too ko leyin omobinrin.

A gbo pe fasiti FUNAAB ni Ferisope sese wole si, gbogbo awon ore e ti won lawon jo lo sileewe girama FCE ni won so pe eeyan jeje ti ko feran wahala ni, bee ni won so pe oun lo maa n lewaju ninu soosi ti won ba fe se nkan nitori to tun wa ninu egbe akorin.

Oro amoran tawon kan si fi n ranse ni pe ko ye kawon eeyan maa bo ara won mole taisan ba n se won, se lo ye ki won lo si osibitu ki won si tun maa fadura tii ilera won nidii, nitori pe iru awon nkan bayii ma n fa iku aitojo ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI