Oludije
fun ipo gomina ipinle Ogun lodun 2015 ati oludasile ajo alaanu Paseda Legacy
Foundation, Omoba Olarotimi Olatunde Paseda ti pariwo sita pe oun ko darapo mo
egbe oselu Accord tawon eeyan n gbe kiri.
Paseda
soro yi ninu atejade ti akowe iroyin e, Ogbeni Michael Ogunsiji fi sowo
s'AWIKONKO lai pe yi, o ni iro ati aheso to jinna si ooto niroyin ayederu
naa.
AWIKONKO
gbo pe pelu bi egbe oselu Accord se n gbile si kaakiri ipinle Ogun, paapaa
lorileede Naijiria, tawon oloselu si n sare loo foruko sile lati rowo mu ninu
idibo odun 2019, lo fa a tawon eeyan fi ro pe gbajumo oloselu naa ti n gbero
lati loo darapo egbe oselu Accord.
Ninu
atejade naa lo ti so pe aheso naa kii se ooto rara nitori pe Omoba Rotimi
Paseda gan an ni eni igi leyin ogba to n sagbateru egbe oselu Unity, UPN
kaakiri orileede Naijiria.
O
ni bi eyikeyi ayipada ba fee waye ninu egbe oselu UPN, tabi to jo mo oro oselu
nipa oun, oun yoo je kawon araalu mo nipa e.
Bee
lo gbawon araalu lamoran pe ki won ma se ni iporuru okan, tabi se iyemeji
latari awon ayederu iroyin to n lo kaakiri ori ero ayelujara, intaneeti.
No comments:
Post a Comment