Opo awon to gbo
sisele baba agbaaya eni odun merindinlaadota, (46), Ezekiel Adegbenga to fipa
ba omo to je ko je gege bi omoomo e lopo n'Iyana Ilogbo, Ota ipinle Ogun lo n
so pe a fi ko ku sewon, nitori bo se baye omolomo je lati kekere.
Ojule kerin, adugbo
Olufunmi Ajayi nisele naa ti waye ni nnkan bi aago merin irole ojo Wesde ose to
koja yi nigba ti won so pe asiri Ezekiel tu si iya omo naa lowo.
Ohun taa gbo ni pe
iya omo yi lo sakiyesi awon ayipada kan lara omo e lasiko to n we fun un niwaju
ita ile won, nibe la gbo pe o ti beere awon oro kan lowo e, tomo naa so pe Dadi
lo se kinni foun.
Obinrin yi ko koko
gba omo e yi gbo pe boya ko mo nnkan to n so, sugbon bomo naa se m soro lo je
ko yee pe ko si iro ninu nnkan to n so jade lenu.
Bo se di pe o pariwo
sita pe kawon araadugbo gba oun, Ezekiel ti baye omo oun je, o ti fipa bomo oun
sun.
A gbo pe Ezekiel ko
si nile lasiko naa, igba to maa pada wole ni nnkan bi aago meje irole, Oju ona
ni won ti gbe ija ko o, toro naa si di isu ata yanyan.
Eni to ta wa lolobo
je ko ye wa nise ni Ezekiel koko se ni eni ti ko mo nnkankan, tawon eeyan si ni
ki won gbee lo tesan, ibe lo ti maa jewo towo olopaa ba te e.
Looto nigba ti won
de be la gbo pe Ezekiel ti so fawon olopaa pe ki won se oun jeje nitori pe ise
esu ni. O lasiko tawon obi omo yi jade jade loun dogbon tan an wole lati ran an
nise.
Bee lo so pe igba
kan pere loun se kinni naa fun, no tile je pe oun ko le so emi to gbe ounje wo
lojo naa, nitori pe leyin toun se tan loju oun too da. Lesekese lo so pe oun ti
be omo yi pe ko daso asiri boun, ko ma so fenikan, toun si ra nkan fun.
Ahmed Iliyasu to
keep komisana olopaa ipinle Ogun nigba to gbo soro naa lo ti pase pe oun fee
foju kan an, ti won si gbee e lo ba a ni Eleweran nibi to to n gbategun
bayii.
Bo tile je pe
Iliyasu ti tare e sodo eka olopaa to n ri si lilo omo nilokulo, sibe o ni
lai pe ni Ezekiel yoo foju bale ejo latigba idajo to to sii.
No comments:
Post a Comment