Pakopako ni Baale abule Ososun
nijoba ibile Ifo ipinle Ogun, Isiaka Ajani n wo logba olopaa leyin tasiri e tu
sita pe oun gan an ni olori awon babalawo to n ra eya ara eeyan fi seso fawon
eeyan.
Boroboro ni Baale naa n ka bi eye
ayekooto nigba ti won mu pelu awon ogbologbo elegbe okunkun ti won ni won o
nise meji ju ki won maa sowo eya ara eeyan lo tasiri won tu sita.
Ohun taa gbo ni pe agbegbe Ibogun
ni Ifo lowo olopaa ti te gbogbo won ti won si so gbogbo ise ibi ti won ti se
seyin ko too di pe okete won ko ri ona lati boru mo.
AWIKONKO gbo pe bawon eeyan yi se n
segbe okunkun, ni won n digungbale, bee ni won tun n digun jawon araalu lole,
ti won tun n fipa bawon odomobinrin to ba ko sakolo won sun bo se wu won.
Oluwaseun Odueh ti won tun n pe
ni Cleff ati Wasiu Adejumo ti won n pe ni Bomber lawon omo egbe okunkun Eiye yi
ti won ka owo eeyan mo lowo lose to lo lohun, ti won si tu asiri ise won fawon
olopaa, awon gan an ni won satona awon olopaa bi won se mu awon babalawo meji
to fi mo baale naa.
Ajani nigba to n soro kabamo iwa
naa, to si ni ki won foju aanu wo oun, ati pe ise esu ni. O ni ajagungbale
lawon eeyan naa koko pe ara won nigba ti won wonu abule wa, ti won si lawon fee
soogun ibile.
O so pe ko pe ti won de ni won
tun so pe awon n ta eeya ara eeyan, paapaa apa. O ni nigba toun rii pe o maa
wulo fawon ise kan, lo je koun ra apa meji legberun mewaa, sugbon toun ko mo pe
asiri si maa tu.
Awon babalawo meji towo tun te,
Ifatona Akanni tawon eeyan n pe ni Ajana Oro ati Oko Musa so pe apa meta-meta
pere lawon ra lowo awon eeyan naa, ati pe oogun asiri bibo lawon fi awon apa
naa se, egberun marun lawon si n ra apa kan soso lowo won.
Musa so pe looto loun n sise
babalawo tawon eeyan si mo oun, O ni ninu apa meta toun ra, owo apa meji pere
loun si ri san, egberun marun naira to je owo apa kan lo ku toun fe e fun won
ko too di pe won wa mu oun nile.
Okan lara awon odaran naa, Odueh
so pe omo egbe okunkun Eiye loun, o ni kii se pe awon deedee maa ta apa awon
tawon ba pa, sugbon kawon le maa fi ri owo naa lati fi mu idagbasoke ba egbe
won lo je kawon bere si ni maa ta a fawon babalawo.
Bee ni Wasiu eni ogbon odun, to
tun sise yahoo-yahoo so pe oun ti pa eeyan meji ninu egbe okunkun alatako,
Aiye, iyen Kehinde ati Lekan Welder, ti won pa lara awon omo egbe won, ti won
tun ge apa won lo.
Ni bayii, agbenu funleese olopaa
ekun Zone 2, Arabinrin Dolapo Badmus nigba to n soro so pe ni nnkan bi aago
meji osan ojo ketalelogun osu to koja lowo te Oluwaseun Odueh, to si jewo
fawon, ko too di pe owo te awon emewa e to ku.
O l’ose yi gan lawon eeyan naa
yoo foju bale ejo nitori tawon eeyan naa ti jewo, ti tun si nnkan tawon n duro
de gege bi igbakeji oga olopaa ekun Zone 2, Adamu Ibrahim se ti pase fawon.
No comments:
Post a Comment