Awon oni fayawo koju ija sawon eso asobode l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 30, 2017

Awon oni fayawo koju ija sawon eso asobode l'Ogun

Nise loro di boo lo o yago lona lojo Abameta Satide to koja lo lohun nigba tawon oni fayawo atawon eso asobode (custom) koju ija sira won lopopona Olorunda si Idiroko nijoba ibile Yewa South ipinle Ogun, nibi ti won lawon eeyan ti farapa yannayanna.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won so pe fun bii wakati meta gbako lawon eeyan naa fi ja ija igboro naa nigba ti won so pe awon oni fayawo ni won deede loo kolu awon osise eso asobode lakoko ti won n sise won lowo.

Ohun ta a gbo ni pe, won ni wahala tawon eso asobode naa n fawon eeyan lagbegbe naa ti poju, ati pe awon ti won ba mo ni won n je ki won se fayawo raisi wole bo tile je pe pelu egunje ti won gba lowo won ni won fi n fun won laaye.

A gbo pe owo ti won lawon eso asobode naa tun n beere lori raisi kan ti won ba gbe ti po ju owo ti won n gba lowo awon ti won n ba se fayawo raisi naa lo, eyi lo si je ki won pinu pe a fi kawon ja feto awon bayii.

Lojo naa la gbo pe ojiji ni ikolu naa je fawon osise asobode yi ti won so pe jeje won ni won n koja lo, ko too di pe awon eeyan naa to le ni ogorun loo kolu won pelu orisirisi eroja oloro bii ada, obe, oogun abenugongo atawon nkan min in.

Gege bi eni kan to wa lolobo se so, o ni ere lawon osise asobode naa koko pe e sugbon nigba ti won ri owo tawon eeyan naa gbe wa ba won, lo je ki won na papa bora, nitori taa gbo pe bi won se n yinbon lu won ni ko wole.

Eni naa so pe nigba tawon osise asobode yi sa asala Femi won tan ni won fi raaye lati ba moto won je, ti won fo gbogbo gilaasi ara e, bee ni won tun jo taya mereerin to wa lese e.

AWIKONKO tun rii gbo pe asiko tawon osise asobode sawon igbo ni won fi ranse sawon eeyan toku, ti won tun te awon olopaa ati soja laago lati was daabo bo Emi won, sugbon ki won too de be, awon eeyan naa ti lo.

Ni bayii ohun taa gbo ni pe owo olopaa ti ba meta ninu awon olokada to n se fayawo yi, ti won si tun ti gba okada ti ko din ni metadinlogun, iyen lasiko taa n sakojopo iroyin lowo.

Oga Agba fajo eso asobode nipinle Ogun, Ogbeni Sani Madugu nigba to n soro so pe ko si nnkan meji to je kawon eeyan naa maa binu bi ko se bawon se pase pe won ko gbado se fayawo raisi wole mo, tawon si ti loo dina mo won lawon ona ti won maa n gbe ise fayawo won gba.

O lawon gba moto mejo, eyi ti meji ninu e je tokunbo to je pe raisi nikan I won ko sinu won bamubamu, ati pe ibi ti won ti n ko raisi sinu Awon moto naa lasiri won ti tu sawon lowo.

Madugu so pe awon sense bere igbogun ti pelu awon eeyan naa ni nitori tawon ko nibi foju boro bawon se mo, ati pe eni towo palaba e ba ti segi, ile ejo lawon yoo gbe e lo.

Iwadii fi ye wa pe lati ojo Sande to koja lo lohun ni ko ti seni to le gbe raisi wole mo, won ni se lawon oni fayawo naa paaki moto won kaakiri inu abule lati abule Alapoti titi de Ado ni won fi paaki awon omo to je pe raisi nikan lo wa ninu e si, ti won n reti ojo tawon yoo raaye gbe e lo sibi to n lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI