Titi di bi
e ti n ka iroyin yi lawon eeyan to gbo sisele awon olopaa Gomina ipinle ogun,
Ibikunle Amosun si n so pe oro naa kii soju lasan latari bawon eeyan naa se ku
laarin ojo merin sira won.
Olayinka Robot |
Gege b’AWIKONKO
se gbo, Busoye Olayinka ati Wale Aderemi lawon eeyan naa ti won so pe okan
pataki lawon mejeeji ninu awon olopaa to n tele Gomina Amosun, toun naa ko si
le fi won sere.
Ojo Aje
Monde ose to koja la gbo pe Wale Aderemi, omo bibi ipinle Ekiti to n sise lekaa
DSS dagbere faye losibitu Mercy, to wa ni Panseke Abeokuta leyin ti won loo
subu nile igbonse inu ile to n gbe.
AWIKONKO
gbo pe aisan taifoodu lo se Wale, ti won si fun laaye pe ko loo toju ara e
losibitu nibi to tii lo ojo meloo kan, ko too di pe won ni ko maa lo sile. Aaro
ojo Monde naa nigba to je pe koun loo fo enu, la gbo pe ese e gba ilekun, to si
subu lule.
Lesekese
lawon ti won jo n gbe e ti sare gbe e pada lo si osibitu Mercy naa, sugbon
nigba ti won maa gbe e de be, elemin in ti gba a. Aaro ojo Tosde to koja la gbo
pe won gboku e lo sipinle Ekiti to ti wa.
Ironu iku
Wale lawon elegbe e si n ro lowo laaro ojo Fraide, nigba ti iroyin iku Busoye
Olayinka tun fi kan si won, pe o pada emi e ninu ijamba moto lagbegbe Papalanto,
nitosi Ewekoro.
Ohun taa
gbo ni pe oun ati aburo e kan ni won jo n rin irin ajo lo sile e taa ko tii gbo
ibi to wa titi dasiko taa fi sakojopo iroyin yi tan leyin to kuro nibi ise e ni
nnkan bi aago mesan ale ojo Tosde naa.
AWIKONKO
gbo pe idunnu owo ti Gomina Amosun sese fawon to ba a sise lale ojo naa lo n
gbe e lo sile lati loo fawon ebi e ninu e, ko too salabapade iku ojiji pelu
aburo e ti won lesekese loun naa ti ku.
A gbo pe
oko tirela kan lo n feyin rin jade ninu ogba Dolphin Steel Nig. Ltd jade si
titi, iyalenu lo je nigba ti Olayinka tawon eeyan tun n pe ni Robot maa fi
gboju soke, aso ko bomoye mo, abe tirela naa ni moto e Nisaan Primera pelu
nomba idanimo Lagos, PH 406 KJA mori wo.
Oga agba
ajo FRSC nipinle Ogun, Ogbeni Ckement Oladele nigba to n jeri soro naa so pe bo
tile je pe kii se lesekese ni Olayinka ati aburo e ku, sugbon bawon se n gbe
won wonu ogba osibitu ijoba to wa n’Ifo ni won dagbere faye.
Bawon eso
Gomina Amosun se gbo sisele yi leru ba bere sii bawon, ti won beere lowo ara
won pe taniku kan, nitori teru ti bere sii ba gbogbo. Onikaluku won la gbo pe
won ti bere sii pe ohun ti won nigbagbo ninu e fun aabo.
No comments:
Post a Comment