Ko si iroyin meji to
n lo kaakiri orileede Naijiria to fi mo awon orileede kaakiri ile adulawo (Afrika) bayii, bi ko se ti ikojade iwe
tuntun tileese iwe iroyin Alariya Oodua, iyen iwe iroyin to n sagbelaruge ewa
ati asa Yoruba pelu ajosepo egbe awon oluko lawon ileeko olukoni fee gbe jade ninu osu kokanla odun yi.
Iwe tuntun naa ti
won pe akole e ni “YORUBA NI TOOTO”, ti Ogbeni Kunle Babarinde to je olootu
agba fun iwe iroyin Alariya Oodua ko, la gbo pe won fee se ikojade e ni gbongan
nla kan to fikale sinu ogba ileewe tawon oniroyin, Nigeria Institute of
journalism to wa legbe Oteeli Excellent lagbegbe Ogba nipinle
Ekoo l’ojobo Tosde, ojo kerindinlogun osu kokanla (November 16th,
2017).
Gege bi atejade to
te AWIKONKO leti lai pe yi se so, won ni aago mejila aaro ni won yoo tepepe eto
nla naa tawon ojogbon kaakiri orileede yi ti gbaradi fun ni won so pe gbogbo
eto lo fe e pari bayii lati mu ojo naa larinrin.
Lara awon asiri to je
ki iwe naa da yato si tawon iwe abinibi to so nipa itan ile Yoruba ti won ti ko
seyin ni bi won se so pe egbe awon oluko nileewe olukoni, iyen Koleeji kaakiri
orileede yi sise takuntakun lori e lasiko ti won n ko o lowo.
AWIKONKO gbo pe
Omowe S.M Raji to je aare egbe awon olukoni nileewe olukoni, NCE lorileede yi
lo bu owo lu ojo naa leyin opolopo ipade to ti waye laarin egbe naa pelu ileese
iwe iroyin Alariya Oodua to fi mo awon ojogbon nipa eko ede Yoruba.
Asiri min in to tun je pataki ti won lawon ojogbon se yan iwe naa laayo ni awon akatunka, akafikogbon awon itan Ife pelu Modakeke, Alaafin Oyo, ilu Ibadan, Alaafin Arole to fi mo itan bawon Fulani se gba ilu Ilorin mo awon omo Yoruba lowo titi donii.
Nigba to n soro,
Omowe S.M Raji je ko di mimo pe akoko iru e nile Yoruba niwe “Yoruba Ni Tooto”
je, ati pe idi tawon fi gba iwe naa lowo eni to koo, iyen Ogbeni Babarinde ni
ojo ola tawon ri ninu e, tawon si lo osu meta gbako lori e, pelu opolopo ise
iwadii atawon amuye to ye lori lati le je itewo gba lowo awon to ba salabapade
e.
AWIKONKO gbo pe lara
awon to ti n mura sile fayeye ikojade iwe naa ni Oba Adeyeye Ogunwusi, Ooni Ile
Ife ati Oba Saliu Adetunji to je Olubadan tiluu Ibadan ti won maa lewaju gbogbo
Oba alaye nile Yoruba lojo naa, nigba ti Akeweje tiluu Iseyin, Alaaji Razak
Adeleye tawon eeyan tun mo si “Agba Awo” maa je alaga ojo naa.
Alaaji Ganiyu Ajibola,
iyen Akewusola ni olufilole agba ojo naa, nigba ti Iyaloja gbogboogbo, Oloye
Folasade Tinubu Ojo; Oloye Toyin Kolade ati Alaaja Fatimot Mojisola Sanni maa
je awon iya ojo naa.
Oga agba fun ajo OPC
lorileede yi, Otunba Gani Adam ni oludanilekoo pataki ojo naa, nigba ti agbenu
fun Aare Buhari, Ogbeni Femi Adesina lo maa salaye awon itan to wa ninu iwe
tuntun yi fawon alejoo. Bakan naa ni olootu agba fun ileese iwe iroyin Vanguard
lo maa fiwe naa lole.
Ohun taa tun gbo ni
pe minisita foro iroyin ati asa lorileede yi, Alaaji Lai Muhammed lo maa je
gege bi alejo pataki nibi ikojade naa, ti gomina ipinle Osun, Rauf Aregbesola
yoo soju gbogbo gomina ile Yoruba.
Gomina tele nipinle
Ekoo, to tun je asiwaju egbe oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni baba ojo
naa.
AWIKONKO gbo pe
nnkan ti yoo tun mu ayeye ikojade Yoruba Ni Tooto larinrin ni ti won fee fun
lami eye awoodu, iyen awon taa gbo pe won ti ko ipa ribiribi nipa itesiwaju ede
ati ile Yoruba lapapo.
No comments:
Post a Comment