Adajo ni ki won fi Sulaiman to ji adie pamo sogba ewon - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 30, 2017

Adajo ni ki won fi Sulaiman to ji adie pamo sogba ewon

“E foju aanu wo mi” loro ebe to tenu odomokunrin eni odun mejilolelogbon, Sulaiman Ajo jade niwaju adajo ile ejo Majisireeti to wa ladugbo Isabo Abeokuta lose to koja pelu esun orisi meji ti won fi kan an.

Ohun taa gbo ni pe Sulaimon lo wonu oko adiye okunrin kan ti won poruko e ni Ibrahim Mutiu, to si ji adiye mejidinlologoji gbe ladugbo Ita-Oshin.

AWIKONKO gbo pe ojo meta gbako ni Sulaimon fi ji awon adiye naa gbe, iyen ojo kerinla, ojo ketadinlogun ati ojo kokandinlogun osu kerin odun yi, sugbon ti won lasiri e tu leyin ojo keta ti won ti n wa a.

Nigba ti Ibrahim rii pe ojoojumo lawon adiye oun n din, lo ba bere ise ojulalakanfinsori funra e pelu awon kan, ko too di pe owo palaba e segi, ti won si gbe e lo si tesan olopaa.

A gbo pe opolopo ebe ni ba okunrin naa be, sugbon ti won ni Ibrahim so pe a fi koun gbe e lo sile ejo, nitori pe ileejo lo le pase boya ki won fi sile.

Awon adiye naa la gbo pe owo won ko din ni egberun mejilelogota, (N62,000). Sulaimon nigba ti won n beere oro lowo e so pe looto loun jebi esun ti won fi kan oun, sugbon ki won foju aanu wo oun nitori pe oro atije lo sun oun de be.

Nigba to n soro, Onidajo Oriyomi Sofowora so pe ki won si fi pamo sogba ewon titi dasiko toun yoo fi pinu oun toun fee se. o wa sun igbejo min in sojo kessan an osu to m bo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI