Toko tiyawo to fee fomo soogun owo wo gau - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 25, 2017

Toko tiyawo to fee fomo soogun owo wo gau

Atimole olopaa ni won wa bayii


"E dakun e se wa jeje" loro ebe to n jade lenu awon odaju abiyamo meji kan, Nasiru Adeyemo atiyawo e,  Idayat Adeyemo ti won ni won fee fomo won,  Abibat Abike Adeyemo seso lago olopaa to wa ni Eleweran niluu Abeokuta lojo Aje Monde ose to koja.


Bawon araadugbo to gbo sisele naa se n fepe ranse soko atiyawo naa, bee lawon kan tun n so pe ori omo yi,  ti won loo sese pe omodun meje ko gbabodi lo je ki won loo gbe e ju sinu igbo. 

Gege b'AWIKONKO se gbo, won losan ojo Sannde ose to koja lawon araadugbo Asabala loju ona Papalanto siluu Sagamu sakiye apo saka kan to n min legbe titi, eyi to fee ko iberubojo bawon eeyan.

Bo tile je pe eranko ni won koko ro pe won di sinu apo naa tele,  sugbon igba ti won tuu,  to won rii pe eeyan lo wa nibe,  anjoonu lawon kan tun ro bii. Eyi lo faa ti won ni won fi ranse sawon agbaagba atawon odo to laya ladugbo lati waa ba won wo nnkan to wa ninu apo naa. 

Ninu oro ti okan lara awon araadugbo naa to b'AWIKONKO so lori aago laaro ojo Isegun Tusde to koja yi,  eni to ni ka foruko boun lasiri naa so pe obinrin kan to n koja lo laaro ojo naa lo sakiyesi apo saka naa,  to si fi to awon eeyan leti. 

Eni naa je ko ye wa pe lati ojo Eti Fraide ose to lo lohun ni apo naa ti wa nibe,  sugbon tawon eeyan ko fura pe eeyan ni won di sinu e.

 O so pe ero okan opo awon eeyan to n koja legbe e ni pe ile lasan ni won di sinu nitori pe se lawon eeyan maa n di ile sinu apo,  ti won a si gbe segbe titi fawon to n ko ile lati gbe e lo danu. 

Awon ti won mo omo naa lo so pe awon mo awon obi e, ati pe isele naa ko le seyin won, eyi lo faa ti won loo fi mu awon mejeeji nile lati for wa won lenu wo. 

Bee ni enikan toro naa tun soju e so pe iyalenu lo je pe eeyan lawon ri ninu apo tawon ro pe ile lasan lo wa ninu e. 
 
Ninu oro Obinrin naa,  o so pe "Lati ojo Fraide ni apo yi ti wa nibe, ero okan awon to n gba egbe e koja ni won ro pe ile lo wa ninu e.  Igba tenikan to n koja loo tii le apo naa n min, lo fi pakiyesi awon eeyan si i. 

"Eranko bi aja tabi ewure la koko ro pe o wa ninu e. Awon odo ni won tu u to won si rii pe omo kekere lo wa ninu e. Aya wa ti ja,  anjoonu la koko pe,  sugbon bomo b naa se n se lo je ki won mo pe eeyan gidi ni."

Ninu oro ti won ni Abibat so lo ti je ki won mo pe baba oun atiyawo e ni won ge okan ninu ika owo oun

O tesiwaju pe lesekese lawon to da omo naa mo ti loo ranse le awon obi e lati wa won nnkan ti won,  sugbon iyalenu lo je pe bawon eeyan naa se se lo je ki won fura si won pe ko seyin won. 

Eyi lo faa ti won fi woo won lo siwaju awon agbaagba pe ki won so tenu won, nibe ni won si ti jewoo pe Ki won se awon jeje nitori pe ise esu ni. 

Won ni se lawon mejeeji tun bere sii tako ara won nigba ti Nasiru so pe iyawo oun lo ni kawon loo fomo naa seso,  sugbon nigba ti won rii pe ori e ko gbabodi lo je kawon di sinu apo,  ko le tete ku. 

Idayat so pe iro lo pa moun nitori pe oun ko mo ile babalawo kankan to le mu koun so pe kawon loo fomo naa soogun owo. 

Loju ese ni won so pe won ti loo fa won le awon olopaa Owode Egba lowo lati fese ofin too. Ko pe ti won fi gbe awon mejeeji de tesan ni komisana olopaa ti pase pe ki won maa ko won bo ni Eleweran. 

Bawon kan tun se n so pe iya Abike ti ko Nasiru sile lati nnkan bi odun meta seyin,  bee lawon kan n so pe Obinrin naa ti dagbere faye sugbon ti a ko tii le fidi e mule titi di asiko ti a n sakojopo Iroyin yi. 

AWIKONKO gbo pe awon eleyinju aanu ni won gbe Abike lo si osibitu ti won loo ti n gba itoju titi di asiko ti an sakojopo Iroyin yii lowo. 

Ni bayii, komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti tare won sodo eka olopaa to n ri soro ajinigbe ati egbe okunkun lati tubo foro wa won lenu wo,  bee lo so pe a fi kawon mejeeji foju bale ejo. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI