Okunrin kan eni odun
mejilelaadota,Kehinde Onayiga to pe ara e ni Wolii ti so pe kawon eeyan maa pe
oun niranse Olorun, nitori Esu loun sise fun un, boya si ni oun le ri idariji
gba lati odo Olorun.
Lojobo Tosde ose to koja, lawon olopaa
safihan okunrin yii peluu Musiliu Jubril lori esun pe won ji omobinrin, omo
odun mokanla gbe ti won ko si ti ri omo naa titi di akoko yii.
Gege bi AWIKONKO ti gbo niluu Sagamu
lowo ti te awon eeyan naa, iwadii fi ye wa pe Odomokunrin to n gbe lodo Pasito
yii lowo koko te lori esun omo ti won ji gbe naa.
Oun lo wa ni kawon olopaa se oun
jeje,nitori pe Wolii Kehinde lo ran oun nise pe ki oun ba oun wa omobinrin ti
ko ba ti balaga wa, oun fee fi sise fawon omo yahoo ti won je onibara oun.
Musiliu naa lakoko to n ba oniroyin wa
soro ni Eleweran lose to koja naa tun jewoo pe ise birikila loun se, ati pe
soosi Wolii Kehinde loun loo, o ni bo se be oun nise naa, to si seleri foun pe
oun yoo foun ni egberun lona ogun naira, lo je koun tete jara mo.
O tun salaye pe omobinrin kan tawon jo
n gbe loun dogbon ni ko sin oun loo sinu oko, oun fee loo ko igi, boun se tan omo
naa loo sodo Wolii naa niyen, toun ko si mo nnkan to fomo naa se.
Nigba tasiri tu tawon olopaa mu oun
loun jewoo pe Wolii Kehinde lo be oun nise naa Sugbon Wolii naa so pe iro ni
eni naa pa mo oun, loooto lo so pe oun mo on ri, o ni omo iya ijo oun ni, odo
oun lo si n gbe.
Bakan naa lo tun so pe nnkan to ba oro
naa je ati pe Olorun to fee tu asiri oun ni awon ogun abenugangan toun fi sise
wolii oun, ti won ba nile oun. O ni o ti to bi odun metadinlogun toun ti di
Wolii toun si ni soosi Kerubu ati Serafu, Agbo Jesu to n dari, peluu awon ogun
to n loo naa.
Se ni Kehinde tun jewo pe Alfaa kan ni
Sagamu toun ti koko wa lodo e,koun to di igbagbo osan gangan loun ti gba awon
ogun dudu toun lo yii, o si ti pe toun ti n loo.
O so pe peluu gbogbo nnkan to sele yii,
oun mo pe Olorun ko lo pe oun.Ni bayii, Komisanna awon olopaa nipinle
Ogun,Illiyasu Ahmed ti so pe nigba tawon yoo ba fi pari iwadii awon,Wolii atomo
eyin e yii, yoo jewoo ibi ti won gbomo naa pamo si.
No comments:
Post a Comment