Paseda seto eko fawon omoleewe lakoko isinmi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 14, 2017

Paseda seto eko fawon omoleewe lakoko isinmi

Bo tile je pe erongba awon obi omo min in ni lati wa owo ti won yoo fi ran awon won ni lesini lakoko isinmi ti won wa yii, sugbon ti won ko lagbara e, amo bayii,erin ti bere si nii pa eeke won, nitori bi oludije fun ipo gomina labe egbe oselu UPN, Omooba Rotimi Paseda se seto naa lofee to si ti bere.

Paseda
Lojo aje Monde ose yii ni won bere eto eko naa lofe nibi tawon omoleewe bi egberun lona merin ti n jafaani e kaakiri ipinle Ogun, bi won si ti n kekoo naa bee ni won tun fun won ni iwe ati ikowe lofee.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni okan lara erongba Omooba Rotimi Paseda lati rii pe eto eko di irorun fawon omoleewe,gege bi Oloye Obafemi Awolowo se se nigba to wa laye lo mu koun naa rawole eto bee,

Ona meedogun la gbo pe won yara ikekoo awon omoleeewe naa si lawon bii Abeokuta, Ijebu Ode, Omu Ijebu, Yewa atawon ibo min in, gbogbo ibe naa si lawon oluko ti won gba lati wa da won lekoo naa wa.

Lara awon ibi ti lesini naa ti waye ti oniroyin wa sabewo de lojooru Wesde ana ni awon ibi meta to wa niluu Ijebu Ode ati ibi kan soso to wa ni Omu Ijebu, opo awon omoleewe naa ni won fi idunuu won han si eto naa, ti won si dupe lowo Paseda.

Opo awon omoleewe naa lo so foniroyin wa pe bi Paseda ba le di gomina lodun 2019 awon mo pe eko yoo di irorun fawon, bee ni won so pe bawon se je omo kekere to, awon setan lati bere ipolongo fun okunrin naa, nitori o n fee ilosiwaju rere.

Nigba ti Rotimi Paseda ba oniroyin wa soro, o seleri pe gbogbo igba tawon omo naa ba ti wa nisinmi niruu eto bee yoo maa waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI