Oro beyin yo: Egbe oselu APC fepe ranse si Gomina Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 1, 2017

Oro beyin yo: Egbe oselu APC fepe ranse si Gomina Amosun

Bee lawon omo egbe tun yowo ese sira won

Gomina Amosun
Kayeefi loro awon omo egbe oselu All Progressives Congress niluu Ikenne, nipinle Ogun si n je fawon to gbo nipa wahala kan to sele nibi idibo to ye ko waye, sugbon ti won ni Gomina Ibikunle Amosun ti foruko awon to fe ki won gba ipo naa ranse.

Gege b’AWIKONKO se gbo, ojo Abameta Satide to koja yi ni wahala naa seyo nitori Ipade gbogbogbo tijoba ibile nibi to ye ki won ti dibo yan awon oloye tuntun ti won ni won fee.

Ohun ti a gbo ni pe kaka ki won je kawon  omo egbe naa dibo yan eni to wu won, se ni won kan yan awon eeyan kan, eyi ti ko dun mo awon eeyan naa ninu, to si je ki won fehonu han lesekese.

Bo tile je pe awon omo eyin Oloye Olusegun Osoba ti won wa ninu egbe naa ko tie kopa rara nitori ti won ni awuruju ni eyi ti Amosun atawon eeyan e se lojo Abameta Satide naa.

Sugbon iyalenu lo tun wa je pe eyi tawon omo eyin Amosun se naa, epe ni won fi ranse si oga won, nitori bi won se ni oun lo foruko awon eeyan yi ranse lawon ijoba ibile naa.

AWIKONKO gbo pe se lawon kan bere sii ju aga lu ara won nigba tawon min in si yowo ese si ara won pe awon ko nii gba, nigba tawon ti won ni Amosun fi ranse ti ko te won lorun ti won ni ayafi kawon dibo.

Onarebu Odofin-Samuel Sonuga to je asoju omo ile igbimo asofin to n soju ekun Ikenne nipinle Ogun nigba to n b’AWIKONKO soro, o so pe kii se aheso pe won ti ba egbe oselu APC je patapata nipinle Ogun.

O ni ko si ibo kankan nijoba ibile oun sugbon nnkan tawon maa ri ni pe se ni Jamiu Asimi to je alaga egbe naa ni Ikenne ati Kayode Sodiya toun je okan lara awon komisanna Amosun sadeede mu oruko eeyan meta wa, o ni won ni Gomina Amosun lo fi sowo sawon pe eni toun fee niyen.

Onarebu naa so pe oun jeri Amosun pe ko le se bee sugbon o lawon eeyan yen so pe eni kan to n je Adenmosun to je komisanna foro agbegbe lo fi ran sawon, o ni ko ye ko ri bee.

Okunrin naa so pe oun le fi gbogbo enu so o pe won ko je kawon omo egbe dibo yan eni ti won n fee. 

Ohun to n ko awon omo egbe APC tipinle Ogun lominu ni pe bawo ni Gomina se le maa yan le awon lori, sebi won dibo yan oun naa sipo to wa ni ati pe ona lati fo egbe naa si wewe ni won n wa, eyi to je ki won maa fepe nla-nla ranse si gomina.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI