Okunkun ni Buruji Kashamu je ninu egbe PDP – Sikirulai Ogundele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 14, 2017

Okunkun ni Buruji Kashamu je ninu egbe PDP – Sikirulai Ogundele

Alaga egbe oselu Peoples’ Democratic Party, PDP nipinle Ogun, Onarebu Sikirulai Olawale Ogundele ti sapejuwe Senato Buruji Kashamu to n soju ijebu nile igbimo asofin agba nilu Abuja gege bi okunkun to n da egbe naa ru kaakiri ile Yorubaa paapaa julo ipinle Ogun.

Kashamu
Ogundele soro naa ninu iforowero to b’AWIKONKO se lose to koja nile itura kan nilu Abeokuta. O so pe gbogbo wahala to n sele ninu egbe oselu PDP ko seyin Buruji Kashamu nitori pe oun gan an nigi woroko to n dana egbe oselu naa ru.

Ninu oro e, o so pe “Okunkun ati imole ko le joo se papo, won o si le pade lailai, ko seese. Oro Buruji Kashamu atawon eeyan e je omo egbe to je pe ero okan won ko ba ti wa mu. Ero okan ti wa ni pe ka dibo, ka si wole. Ero okan ti won ni pe ki won gbowo lowo otun, osi, oludije, egbe A, egbe B. Okoowo (Business) lawon n fi egbe yi se; awa si n fe ka dibo, ka wole ibo.

“Iyato to wa laarin wa ni yen. A ti ri apeere eyi to sele nipinle Ondo nigba ti Jimoh Ibrahim dide, to je oludije egbe ti Kashamu, to ni kii se pe oun fee wole, sugbon oun kan mon on mo pe koun da egbe ru ni. Nnkan to sele l’Ondo naa lo sele l’Edo.

“Won maa n korin kan pe ‘agaga ri ga, aarun to semi leekan ko tun semi mo, agaaga ri ga’. Egbe ti won ati ti wa, okunkun ati imole ni. Ero wa o papo, nitori e la se so pe ki won lo ro kunle ninu egbe PDP. A ti so o lati inu osu keje to koja, ti a si tun ti gbe igbese min in bayii, ti a si gbo pe won ti n lo sinu egbe Mega.”

Latari aawo to n sele ninu egbe PDP bayii, ati idajo ti won tun sese gba nileejo giga laipe yi, Ogundele tun so pe “A dupe lodo Olorun fun idajo ti ileejo giga julo gbe kale laipe yii, nitori pe idajo naa je eyi to fi wa lokan bale wipe aaye ti si sile lati pari aawo to wa laarin awon omo egbe.

Ogundele
“Awon kan wa ti won pe ara won ni omo egbe to je pe egbe oselu APC lo n lo won, eleyi a fi opin sii. Egbe PDP ti mu ilana lati pada sijoba po. A ti n bawon to see ba soro ninu awon to n fapa janu, ti a ba dibo, o di dandan ko je pe enikan soso lo maa wole, eni ti ko ba wole, inu a bii die, a si ti n be awon to n binu naa pe ki won loo fowo wonu, ki won ma binu mo, ki won je ka jo se egbe naa.

“A dupe pe lara awon ti a ba soro, opo ninu won ti gbo, won si ti pada sinu egbe PDP lodo wa. Sugbon awon ti won o tii pada niisinyin, a rii pe awon ti won ti fi emi won bura fun Ogbeni Buruji Kashamu.”

Nigba to n soro lori ofiisi (secretariat) won tawon Buruji Kashamu fi tipatipa gba lowo won, o nigbese ti n lo lori, nitori pe awon ko fee itajesile ni ko je kawon fee fi agbara gba a lowo won nitori pe itajesile lawon naa fi gba.

Alaga naa so pe nibi to da oun loju de pe owo oun ni adari egbe ipinle Ogun wa, o ni gbogbo nnkan to je mo ti egbe lawon egbe lapapo ti gbe foun, koda ipade tawon se ni ojo Abameta Satide ijeta,oun atawon oloye yooku ni won se itewogba.

Bakan naa ni okunrin tun so pe awon bigba ti Kashamu atawon eeyan e ba n fi akoko sofo loun ka oro won si, nitori awon ti da won duro ninu egbe naa, ti si tun maa loo koju awon igbimo kan niluu Ibadan laipe.

O ni Kashamu ati alaga e, Bayo Dayo kii somo egbe, o digba tawon ba to tun gba won pada, iyen ti won ba yiwa pada ki won to pada domo egbe ipinle Ogun.

Bee lo tun tan imole si pe titi di akoko toun soro yii Ladi Adebutu lawon si mo gege bi oludije fun ipo gomina fegbe oselu PDP nipinle Ogun,o ni Gboyega Isiaka ko tii jade rara. Ati pe awon ko pin ipo gomina si eya kan, enikeni to ba fee dije lati Egba, Yewa, Ijebu ati Remo,won lanfaani lati jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI