Ilu nla
n'Ibadan, ilu isembaye t'itan re daa pupo ni, ko seni je f'Ibadan sere. Ibadan
nilu keta to tobi ju lorile-ede yii, awon eeyan to n gbenu re lowo yii to milionu
meta. Bo tile je pe ile Yoruba ni, sibe kaakiri lati ri awon eya lorisi ti
won tedo sibe, ti won n fibe sebugbe.
Baa se lawon Kristeni la ni awon musulumi,
ti won jo n gbe po lalaafia. Ibe naa laduugbo ti won n pe ni Bodija wa. Bodija
je agbegbe kara-kata bee lawon eeyan n gbebe. O tun je okan ninu awon oja to
tobi ju nipinle naa. Inu Bodija yii kan naa lodo-eran wa, odo eran yii je okan
ninu awon odo to gbajumo gidi, ti awon alapata atawon to n sowo eran ko fi
sere.
Eran je
ohun tawon eeyan feran, awon elesin ati eleya lo n gbadun e. Sugbon t'Ibadan
yato, sasa nibi te e maa lo, te o ni awon ile onje bii buka, tee ma ba orisi
onje pade, bii; amala, eba, ati iyan pelu awon obe lorisirisii
atawon eran ogunfe, eran igbe, eran maalu ati bee bee lo. Iyanilenu ni pe ko si
bi ile olonje naa se le bo si koro to, sasa eeyan le o ni ri nibe. Awon
oloselu, onisowo nla, atawon eeyan to ku die kaato fun. Awon eya eran bii; inu-eran,
fuku, edo, okan, abodi atawon eya ara eran maalu tabi ewure le ma ba ninu
obe won. Ohun t'Ibadan fi n salejo niyen. Ohun abuku ni k'Ibadan ma feran jeun.
Opo awon
ara Ibadan ti won feran eran yii, odo eran Bodija ni won ti n ri i ra. Odo eran
ohun ko si ju irin iseju meji si ogba ileewe giga Ibadan, iyen Yunifasiti tiluu
Ibadan lo, bee naa ni ko je irin iseju marun-un si ogba ileese ijoba Oyo lo. O
je ohun to yanilenu, ti ko se e gbagbo pe iru odo eran Bodija yii, to je ibe ni
gbogbo awon taa daruko yii; ti n ra eran ti won n je senu. Ko se e gbo seti
paapaa. Odo eran Bodija je odo eran kan ti alaafia, ilera ati ohun amayederun
jinna si pupo-pupo, kii se ohun to bojumu rara.
...Ohun
to n sele lodo eran Bodija
ko sohun
amayederun nibe
Ko sohun
to n sise lodo eran Bodija. Ohun amayederun atijo ti won ti se latodun 1986 ti
won ti da a sile naa ni won si n lo. Ko seni to ronu ati fowo tun un se, gbogbo
re lo si ti fee denukole tan. Eedegbeta eeyan lo n sise nibe lojoojumo.
Idoti,
eje, igbonse
Opo awon
idoti ati egbin to n jade lara eran la maa ba pade lodo, awon nnkan bii eje
eran, igbe eran, omi ara eran, atawon idoti inu eran. Bi awon alapata Bodija ti
n ko awon idoti yii jade lara eran, dipo ki won seto bi won ti maa da won nu,
lona imototo, seni won a ko gbogbo idoti naa soju kan, ibe naa ni won ti n pa
eran ti won si ti n fo o, ibe naa ni won ko awon idoti yii si. Idoti tawon alapata
ba sesi da sinu koto idaminu, se lawon idoti yii, lopo igba, maa n loo di gota,
ko kuku seni to n bojuto o. Bee debe, egbelegbe esinsin lo ma ki yin kaabo. Inu
omi idoti gota, ti ko san lo yii naa lawon alapata ti maa n fo eran ti
won fee ta loja. Iwa obun gba a leyi. Bi won ba jaja gbiyanju, ti won ko idoti
jade kuro ninu koto idaminu, iwaju odo ni won maa n ko gbogbo idoti ti won ko
jade si, bee lawon kan si maa n fi ori akitan idoti eran yii sele igbonse won.
Oorun idoti eran ati teeyan to maa n jade latori akitan ko kere. Ewu nla ni
fawon to feran eran.
ko seni
to n ye eran ti won n pa wo
Ohun to
tun ba ajao odo Bodija je ni pe ko si alabojuto fawon eran lodo. Ise tiwon ni
lati bojuto awon eran ti won ko wo odo, lati yewo boya eran teeyan le pa je ni,
paapaa awon nnkan inu eran naa. Sugbon ni Bodija, fun bii odun meji bayii, ko
seni kan to n ye eran ibe wo. Awon oluyewo mewaa pere lo n sise nibe, awon
alapata si le leedegbeta sugbon ojoojumo nija maa n sere laarin won. Idi ni pe
ohun to ba mu ki oluyewo fi so pe eran kan ko to fun pipa, gbese de falapata
niyen. Nitori naa, ogbon ni won fi n bara won lo. A gbo pe ileese aladaani kan
ti ko odo eran mi-in si ibomi-i. Odun 2014 la gbo pe won ti ko o, ohun
amayederun tawon alapata atawon oluyewo nilo lo ti wa nibe, ibe ni won fee fi
tipa ko awon alapata Bodija lo, baa ti gbo. Sugbon titi di asiko yii, se lawon
alapata yari, gbogbo igbiyanju awon agbofinro lati le won kuro ni Bodija lo ja
si pabo.
Awon
eran to larun lara ni won n pa
Iwa
aibikita ati iwa obun po lodo, bii; pipa eran temi ti fee bo lenu e, abi awon
eran to ti ku fun tita. Tita awon eran to larun lara, awon arun bii iko awubi.
Ka maa fo eran ninu omi idoti abi omi eje, igbonse nitosi odo nibi ti won ti n
pa eran. Ka maa jeun nitosi odo, ka maa da ile sibi aito ati ka maa ta awon omo
inu maalu tabi eran to ti ku. Awon alapata kan maa ge ibi eran ti arun wa lara
re, won a ju u senu, ohun ti won n se ni lati mu u da awon onibaara won loju pe
ko sewu loko! Orisi awon iwa odaran lo tun n joba lawon agbegbe yii, awon iwa
bii ise asewo, awon to n loogun oloro, ko si eto ilera kan to dan moran nibe.
Awon nnkan wonyi lo n sakoba fun eto ilera awon araalu.
Ero
repete lodo eran
Ohun to
tun ye ka kiyesi ninu oro yii ni aibowo fun ofin ati bi ko se si eto to peye
lodo. Onikaluku kan n se eyi to wu u ni. Ojoojumo lawon ero maa n wo witiwiti
nibe, onikaluku pelu obe ti won fi n peran lowo. Eni ti o ba mo bo ti ye ko
rin, to rin gbere-gbere, se ni won ma ti i kuro lona. Bakan naa la tun gbo pe
awon alapata kan maa n fun awon eran won ni igbo mu, enikeni to ba duro sona
tiru eran bee ba n bo lodo, inu ewu nla lo wa. Ohun la se maa n ri tawon elomii
ma subu lule, nibi ti won ti n sa feran, elomi si maa n gbe apa lo sile.
Ko somi
nibe rara
Ohun
kosemani loro omi je fun awon odo eran, nitori awon idoti to n ti ara eran jade
ti won nilati fo danu, sugbon oro Bodija ko ri bee rara. Ko somi nibe rara,
laipe yii lawon alapata sese da ogbon si i, ti won gbe kanga. Kanga ohun kii se
eyi to dun un wo loju, nitori a gbo pe se lawon kan maa n se igbonse ninu kanga
ohun.
Ki la
fee se si o?
Awon iwa
aibikita, iwa obun lodo eran Bodija yii lo n mu ka bi ara leere awon oro kan.
Bodija nikan si ko niru awon iwa obun yii ti n sele, bo se wa kaakiri orile-ede
yii niyen. O ye ka beere lowo ara wa - Ki lohun taa n je lara eran wa gan-an
na? Ipa wo lohun ta n je n ko lara ilera wa? Se odo eran to wa laduugbo wa se e
wo loju abi iru ti Bodija naa ni? Ki la le se si i? Bawo la se le daabo bo ara
wa kuro ninu iwa obun to le mu arun ati aisan wa fun wa yii? O tun ye ka beere
ohun tijoba n se lati satunse awon odo-eran wa, ki lawon ijoba atawon
alenu-loro nipa eto ilera le se lati daabobo eto ilera wa, gbogbo nnkan wonyi
lo gbodo lesi.
No comments:
Post a Comment