O kere ninu ore Olorun - Kasnaty - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 25, 2017

O kere ninu ore Olorun - Kasnaty

Ilu mooka sorosoro ori radio ati telefisan tawon aye n kan saara si lasiko yi, Ogbeni Kolawole Adejojo topo awon ololufe e mo si Kasnaty ti fesi oro ranse lori iroyin kan to jade lose to koja latari ti moto ayokele olowo nla meji to ra le ara won laarin osu kan. 

Be o ba gbagbe, lose to koja la gbe iroyin kan jade lori nnkan tawon eeyan so nipa gbajumo sorosoro Kasnaty naa pe oro moto meji to wa laarin osu kan kii soju lasan, sugbon toun naa so pe nnkan ti ko ye opo awon eeyan po ju nnkan ti won lero, boun ko ba si tete soro, o seese ki won tun gba ona min in yo.

Bawon kan se n so pe okunrin naa dogbon soro ara e ni, bee lawon kan n so pe oro okunrin naa nii fura si, ati pe o seese ko ti darapo pelu awon to n se Yahoo-Yahoo. 

Bo tile je pe kii se gbogbo aheso ti a gbo tan la gbe jade sita, sugbon awon eyi ti e ti kaa naa so opolopo oro ninu awon nkan tawon eeyan so. 

Lai pe yi lokunrin naa b'AWIKONKO soro lati fi tako gbogbo oro aheso naa pe kii se ooto, o ni aheso to jinna si ooto lawon nnkan tawon eeyan so nipa oun. 

Ninu oro Kasnaty, o so pe "Ko ye mi bawon eeyan maa n ronu, looto lo dara kawon eeyan maa ri teeyan so lopo igba nitori pe eni taye ko ba ri tie so, laye ti pa ti, Ki Olorun ma je kaye pa wa ti. 

O ni beeyan fi ti oga e, paapaa awon asiwaju e se, ko si nnkan naa to ba dawo le ti ko nii yori si rere fonitoun, nitori pe pelu Idunnu lawon eeyan fi ma maa sadura fun un latokan wa. 

Nigba to n soro nipa asiri to wa nidi oro e, o loun gba foga oun lo je koro oun maa dayo ni gbogbo igba. O so pe nigba toun ra moto akoko, odo oga oun Yemi Sonde, Jigan Akala loun koko gbe e lo.

O ni Yemi Sonde lo sadura orisirisi foun pe oun ko ni fi se asemo. “Nigba ti mo de odo Oga mi Yemi Sonde, o sadura lorisirisi fun mi, to so pe iyanu nla kan tun n bo laipe. Pelu igbagbo ni mo fi dahun adura naa, temi naa si n reti e. Nigba ti Olorun maa gbe ise e de, ko pe osu kan ni Olorun tun pese moto tuntun yi fun mi. Bi mo se ra moto naa, mi o le so o, nitori pe Oba Ara ni Eledumare.”

Kolawole Adejojo tun soro nipa awon awo (color) tawon moto naa ba wa, o ni ko seese lati loot un moto toun ra kun nitori pe awo kan lo mu wa. O so pe orisirisi oda ni moto maa n ba wa, toun ko si le tori nnkan tawon eeyan maa so, koun loo yi oda tawon moto naa ba wa pada.

Bee lo so pe kii se oda ti won loo wa lara awon moto naa ni won so jade. O ni Lexus ayokele toun koko ra, oda eeru (dark ashes) lo wa lara kii se dudu. Ati pe oda waini (wine) lo wa lara jiipu toun ra sikeji, kii se pupa.

O ni moto ti won ro pe oun loun ni, nnkan ti ko ye opo won ni pe iyawo oun, Semmies toun tun n pe ni Ifokanbale lo nii, sugbon nnkan ti iyawo ba ni, oko naa lo nii, bee nnkan toko ba ni, iyawo lo nii, iyen nibi ti ife ba ti n joba. 

Saaju akoko yi lo ti koko menuba ti soosi atawon alaafa ti won so pe oun n tojubo, o so pe aheso to jinna sooto patapata gbaa ni, ati pe asodun atamo oro aheso lawon eeyan n gbe kaakiri nipa e. O so pe awon to ba mo oun yoo mo pe oun kii fi oro esin sere nitori pe adura kii po ju.

Kasnaty ni awon Musulumi toun n ba se po, awon to n foun nidanilekoo lori awon itan nipa Kuraani ni, bee ni won si n gbadura foun nitori pe oun n gbe esin naa ga. Bakan naa lawon Wooli toun n ba rin naa n fasiri Bibeli han oun.

O wa gbawon eeyan lamoran pe ki won ma se maa wa ona lati ba oruko enikan je lai se iwadi to jinle nipa onitohun. Bee lo so pe kawon to n bo leyin ma se ri awon asaaju won fin, ki won ma se maa foju tembelu awon oga won, yala won si wa lodo e, tabi won ko si nibe mo.

O ni boun se n bowo foga oun Yemi Sonde atawon to ju oun lo nidi ise toun yan laayo lo je koun maa tayo laarin awujo.

Nipa ti Oluso e, Wolii Abiodun Akanni ti won so nipa e, Kasnaty so pe nnkan to daa ni pe keeyan ni iranse Olorun to n toni sona nigbagbogbo, to si tun n gbadura fun ni. 

O ni Woolii toun ko le fi sere ni Oluso Abiodun Akanni nitori pe oun gan an lo n to oun sona, to si n gbadura foun loorekoore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI