Ileese olopaa ni ayederu ajaale ni won ri l’Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 14, 2017

Ileese olopaa ni ayederu ajaale ni won ri l’Ekoo

Titi di bi a ti n sakojopo iroyin yi lokan awon omo orileede Naijiria paapaa nipinle Ekoo ati Ogun ko fi bale mo nigba ti won sawari ajaale nibi ti won ti n fawon eeyan soogun owo nita gbangba laarin ilu.
 
Bo tile je pe oga olopade ipinle Ekoo, Fatai Owoseni ti so pe pelu iwadi tawon se e leyin tawon gbo nipa oro ajaale ti won ni won ri lagbegbe Obadeyi si Ijaye loju ona Ekoo siluu Abeokuta lojo Isegun Tusde ose to koja, o fi han daju pe aheso lasan lohun tawon araalu n gbe kaakiri.

O ni yato si eri aridaju tawon rii, orisirisi igbese lo si ti n lo lowo labele lati tubo tan imole sii nitori ri pe aabo emi ati dukia awon araalu lo je awon olopaa logun ju ohunkohun lo, bee lawon si korira itajesile, paapaa lori ona bawon kan se n fawon araalu seso.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni okan lara awon to n gbale loju titi labe ijoba ipinle Ekoo, ti Ogbeni Akinwunmi Ambode ti je Gomina lo sadede n gbo ohun labe kota to ti n gbale, ti won n pari “E gba mi o” lo sare ta kiji, to si pariwo sita pe eemo ti wolu.

Awon araalu ko tete fura, nise ni won ro pe obinrin naa ti ya were ni pelu ariwo to n pa, sugbon awon ti won loye lo sare sunmo odo e lati mo nnkan to n sele, ti won si rii pe ariwo e kii se ere rara.

Lesekese ni won lawon araalu ti ya debe, ti won si ri okan ninu awon ti won n mu lo ninu kota naa gba pada, sugbon ti won niya omo naa ti ba won lo sisale ajaale naa. Ibe ni won ni won ti ri awon bii merin mu, ti won si dana sun lara won kawon olopaa too de lati waa gbawon to ku sile.

Awon eeyan to n dogbon bii were ni won n lo lati fi ji awon eeyan gbe, nitori ti won so pe kii se were meta ni won mu lakoko naa, ti won si rii pe eeyan gidi ni won, ti won si jewo pe awon ti wa lenu e, ojo ti pe.

Lara awon tisele naa soju won tun so pe awon marun un min in ni won tun ri mu to je pe inu kota naa ni won ti jade sita, lai mo pe awon eeyan ti n dode won, nitori tasiri won ti tu sita faraye.

Inu ile akoku kan ni won so pe kota naa tun jade si, tawon eeyan ko si le fura be nnkan to jo be n sele, nitori pe igbo ti kun bo ile naa.

Ni bayii, ikilo ijoba atawon olopaa ni pe kawon araalu tubo maa sise ojulalakanfinsori lawon agbegbe won, bo tile je pe tosan toru lawon fi n sise lati topinpin ibi ti ajaale naa wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI