FUNAAB ti da Bolaji awako won duro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 25, 2017

FUNAAB ti da Bolaji awako won duro

Lose to koja lawon osise ajo to n ri si wole wode, Iyen Custom mu okan lara awon awako ileewe FUNAAB ti Ogbin niluu Abeokuta pelu awon eru ti won so pe igbo ni. 

Agbegbe Olorunda nijoba ibile Imeko Afon, Idiroko ipinle Ogun ni won ni won ti okunrin awako naa mu lojo Satide to koja lo lohun lakoko to n bo niluu Abeokuta. 

Iroyin Owuro gbo pe se ni awako won lo moto FUNAAB fi se fayawo awon eru naa wole nitori ki asiri ma baa tu sita. 

Abiodun Abolade ni won poruko awako naa ti won mu pelu moto boosi Toyota Coasta ti nomba idanimo e je FUNAAB 50 B - 100 FG.

Lesekese ti olori awon ajo Custom yi, Sani Madugu ti fasiri oro naa sita ni igbimo majeobaje, idagbasoke ati isakoso ileewe naa ti pariwo sita pe awon ko mo nkankan nipa e. 

Ninu atejade ti Arabinrin Emi' Alawode to je agbenuso funleewe naa fi sowo si Iroyin Owuro lo ti so pe looto lawon ni awon awako to n bawon side,  sugbon tawon ko le so nipa eru ti won ni won ba ninu moto ileewe naa,  ti won so pe igbo lo kun inu e. 

O lawon ti yo okunrin awako naa, Ogbeni Abolade Bolaji nise, nitori pe se lo doju ti awon, to si fee ba oruko ileewe naa je. 

Boosi naa
Iwe iyoni-nise naa ti nomba e je FUNAAB/R/JP.1804/1/43 lo so pe adele oluforukosile, Acting Registrar, Dokita Arabinrin Linda Onwuka towo bo lati fi le e danu pe ko le bawon sise mo. 

Alawode so pe bawon ajo naa ba se n side iwadii won,  bee lawon naa yoo yan igbimo ti yoo sewadi oro naa. 

O wa tako aheso kan to n tan kaakiri pe awon alase ileewe naa ti kan nipa fawon akekoo won pe ki won ma owo lati fi yanju oro naa ati lati fi towo bowe adehun pelu ajo Custom.

O ni aheso ti ko lese nile lasan ni nitori pe asiko isinmi olude fun saa ikekoo yi lawon akekoo won wa, ti ko si akekoo kankan nitosi. 

O wa fi kun oro e pe iwa omoluabi lo je awon logun, eyi tawon fi n ko awon osise atawon akekoo won kaakiri orileede yi. O mo FUNAAB ko le lowo si iru iwa abuku bayii, atipe awako naa fee fi iwa yi tabuku ba oruko ileewe naa ni. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI