Evans atawon ore e ja ileese MTN lole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 14, 2017

Evans atawon ore e ja ileese MTN lole

Ogba ewon ni won wa bayii

Evans atawon ore e
Titi di bi a ti n koroyin yi lowo lawon odaran mejo towo awon olopaa ipinle Ogun te laipe yi si n ka boroboro lori awon ise ibi ti won n se kaakiri ipinle Ogun, paapaa lori idi ti won fi loo ja ileese MTN lole, ti won ji opo alatagba won.

Gege bi AWIKONKO se gbo, agbegbe kan ti won pe ni Gbalefu nijoba ibile Owode Egba ni opo alatagba tileese MTN naa wa, nibe ni won so pe Tunde Adebayo, Adewole Saheed, Chinedu Eze , Isaac Dele ,Henpery Evans, Emmanuel Otulo, Olaniyan Olayinka, ati Jimoh Idowu ti loo jii gbe.

Ohun taa gbo ni pe okunrin kan to rin sasiko lo sare loo ta awon eso ojulalakanfinsori, Fijilante VGN leti pe awon kan ti n ji opo ileese MTN wu, lesekese ni won lawon yen ti gbera lati loo dawon lowo ko.

Nigba ti won maa de be, se lawon odaran yi koju ija si won, toro naa si di boolo o yago, sugbon leyin o reyin ni won lowo te marun lara won tawon toku si salo. Nigba ti won foro wa won lenu ni won so ibi tawon to ku wa, ti won si loo ko won.

Gbogbo igbese lati ba adari VGN ekun naa soro lo ja si pabo, sugbon olori won nipinle Ogun, Ogbeni Olanrewaju b’AWIKONKO soro, oun lo si salaye boro naa se je fun wa, pe lara awon idanilekoo tawon n se fawon eeyan won lo je ki won ri won mu.

Olanrewaju so pe lesekese toun ti gbo loun ti ni ki won loo fa won le awon olopaa lowo, tawon olopaa si tesiwaju ninu ise iwadii won. O ni gbogbo nnkan ti won ji sinu moto Ford ti won gbe lo, eyi ti nomba idanimo e je EPE 613 DJ ni won gba pada lowo won.

Agbenuso funleese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe looto ni ati pe lara awon eru tawon ri gba lowo won ni kaadi igbowo ATM orisirisi, owo to to egberun mokandinlaadorun (N98,600) atawon eroja ogun ti won fi n sise lorisirisi.

O so pe bo tile je pe awon odaran naa ti jewo pe ilu Ijebu Igbo lawon ti maa n sepade kawon too gbera lo sibi tise ba kan, ati pe kaakiri orileede yi lawon ti maa n sise, sugbon komisana ti pase pe kawon FSARS ko won loo lati tesiwaju. O si seleri pe won yoo foju won bale ejo laipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI