Igbimo isakoso ati
idagbasoke fasiti ogbin, Federal University of Agriculture Abeokuta, FUNAAB ti
ke gbajare sita pe ileewe naa ko lowo si iwa abuku ti won ki kan an lojo
Abameta Satide to koja yii.
Gege bi atejade ti
alukoro ileewe naa, Arabinrin Emi’ Alawode fi sowo s’AWIKONKO lojo Isegun Tusde
onii, o so pe lopin ose to koja ni won lawon kan fesun kan okan lara awon awako
won pe o fi moto ileewe naa ko awon eru to lodii sofin, to si je pe se ni won
se fayawo e wole.
Ninu leta naa, o so
pe, “Won ti pe akiyesi igbimo isakoso ileeko wa si nnkan ti won loo sele lojo
Abameta Satide, iyen ojo kejila osu yii si bi won se so pe okan lara awon awako
wa n lo moto ileewe lati fi ko eru ti ko bofin mu.
“Agbegbe Olorunda
nipinle Ogun ni won so pe awon osise ajo to n ri s’ofin, iyen law enforcement
agents ti mu awako yii pe awon eru to ko sinu moto to je tileewe wa lodin
sofin, to si tun je se loo se fayawo e wole sipinle naa.”
O tesiwaju pe igbese
ti n lo lowo lori e, nitori tawon ti yan awon ti yoo topinpin lati mo boya
looto ni nnkan tawon gbo naa, bo tile je pe awon ko tii le fidi e mule, bee
lawon yoo gbawon ajo naa laaye lati sise iwadii won bo ti to, ati bo ti ye.
O wa fi kun oro e pe
iwa omoluabi tawon fi n sakoso ileewe naa lo han lara awon akekoo won jake-jado
orileede yi.
No comments:
Post a Comment