Oba Sikirulai Kayode
Adetona, Awujale tile Ijebu ti fibinu soro sawon to n gbe iroyin iku e kaakiri
ori ero ayelujara (intaneeti) wipe
ainise lo n dawon laamu nitori pe ko siku loju oun bayii.
Awujale |
Awujale soro yi lojo
Wesde to koja yi lakoko to n ba okan lara awon oniroyin soro lori foonu lati
fidi aheso naa mule latari bi won se so pe Kabiyesi ti waja.
Bi e o ba gbagbe,
lati nnkan ose meji seyin lawuyewuye naa ti n jeyo, sugbon toro naa koja oju
tawon eeyan fi n woo, to si je ki won pariwo naa sita lojo Aiku Sande si Tusde
to koja yi pe baba ti waja.
Kabiyesi ni ki loo
de tawon eeyan n gbe iroyin buruku kaakiri pe oun ti waja, nigba toun wa ni
Oteeli oriental nibi toun ti jaye ori oun.
O ni se lo ye kawon
akoroyin maa fidi iroyin won mule ki won too gbe e jade fawon araalu, paapaa o
ye ki won bere lowo awon oloye oun tabi awon osise to wa laafin oun ki won too
mo nkan ti won maa ko sita.
AWIKONKO gbo pe oteeli
Oriental yi to wa ni Victoria Isalan ni Kabiyesi wa, nibi to ti maa n loo sinmi
leyin to ba loo sayewo ilera ara e nileewosan.
Ohun ti a gbo ni pe
odun metalelogorin 83years ni Oba Adetona, odun ketadinlogota to n lo lori oye
naa re e.
No comments:
Post a Comment