Amosun tun wole awon araalu, won ni ko nife awon - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 25, 2017

Amosun tun wole awon araalu, won ni ko nife awon

Ko seni to wa nibi ti awon omo eyin Ibikunle Amosun to je gomina ipinle Ogun ti n wole awon araalu, to rii bawon eeyan se n gbera sanle, toun naa ko nii ba won kedun lojo naa. 

Ojobo Tosde ose to koja yi lawon eeyan naa tun gbe katakata ti won fi n wole lo si Araromi Ajegunle to wa lopopona Ibadan s'Ekoo, lati loo fi wo ile awon eeyan to wa nibe. 

Ibanuje nla lojo naa je fopo awon araalu toro naa kan nitori pe awon dukia to won fi aimoye odun sise fun ni won loo wo lule mo won lori lojiji, eyi gan an lo faa ti won kan fi bora sihoho lati maa fi Gomina Amosun atawon ebi e sepe. 

Araromi Ajegunle yii ni won so pe o wa labe Makun nijoba ibile Sagamu nipinle Ogun. Gege bi a se gbo, ni nnkan bi aago meje aaro ojo naa ni won ni awon kan dori ile ti won kole si naa peluu awon olopaa kogberegbe ti won ni won ko ibon dani, ti won si bere si ni ko girigiri bo awon eeyan naa.

Won ni nnkan to dun won ni pe won ko tie so fun won tele pe won n bo lojiji ni won de abule naa ti won si bere si nii wo to fi je pe gbogbo ile to wa nibe ati soobu ni won wo pata peluu awon eru won to wa nibe.

AWIKONKO tun gbo pe obinrin kan tie wa ninu ile naa to ni aisan roparose ti ko le jade lati bi odun meloo se won lawon olopaa ti won ko dani ko bikita, se ni won ni won wo obinrin naa sita, ti won si wole e.

Gege bi Ogbeni Micheal Ariyo to je okan lara awon olugbe naa se wi, lojiji lo ni awon eeyan naa de peluu awon olopaa won, ti won si n pariwo pe kawon jade.kawon jade.

Ko si pe tawpn olopaa naa bere si nii yinbon soke lati maa fi le awon eeyan, o so pe opo awon ti won ko si nile ni won wo ile naa leyin won.

Okunrin naa so pe latigba tawon ti ri igbese ti won n gbe yii lawon ti pe won lejoo ni kootu ni Sagamu ti igbejo si n loo lowo, ko to di pe won wa huwa ika yii

Bakan naa ni Baba agbalagba eni odun merindinlaadorin Samuel Ogunyomnbo to n wa ekun mu bi omode so pe nibo ni koun ti bere nitori gbogbo agbekele oun ni won wo yii.

Olawale Olatunde ti ko tii ju OSU meta to ko dele e tuntun naa baraje pupo, o ni Amosun ti so awon di alainilegbe.

Gbogbo awon to tun soro ni won fidi e mule pe ileese to n ri oro ile iyen land ni won wa wo ile naa nitori awon ri meji ninu awon osise won ti won da mo lojo naa.

Ibeeere ti won wa beere ni pe kin ni awon se fun Amosun to fi bawon laye je, to da won pada si ese aaro ati pe nibo lawon ti fee bere. Won wa ro ijoba apapo lati ran awon lowo, nitori gomina naa ti mu opin de ba ile aye awon.

Akoroyin wa de ileese to n ri si oro ile iyen land nipinle Ogun lati ba alakoso agba eka naa iyen Ogbeni Biyi Ismail soro.

Sugbon okunrin naa so pe ileese oun ko mo nnkankan nipa awon to loo wo abule naa ati pe nnkan tawon eeyan naa se buru jai.

O ni loooto lawon gbe igbese lati wo awon ibi to sunmo egbe titi fun atunse oju ona amo kii se gbogbo ile to wa nibe.

Bakan naa ni Arabinrin Yetunde Dina to je akowe agba nileese Urban and physical lawon naa ko mo nipa e sugbon awon ara abule ni alakoso agba foro ile naa ko fee jewoo ni, nitori meji ninu awon osise e lo tele awon olopaa ti won bi Ogun wa lojo naa.

Loro kan awon ara abule Araromi Ajegunle so pe apa ti ko le pare ni Amosun fi sawon lara, Olorun lo si maa se idajo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI