Ileese olopaa ti rowo to awon odaran
meji kan, Chukwudi Okorie ati Nkemjika Nwoke ti won so pe won ko nise meji ju
ki won maa dena de awon onimoto duro lori ere, iyen ni opopona Ekoo si Sagamu.
Awon mejeeji |
Gege bi AWIKONKO se gbo, ogunjo osu to
koja ni won lawon kan loo ta awon olopaa ekun Sagamu lolobo, ti oga
olopaa to wa nibe iyen DPO si ran awon olopaa kogberegbe FSARS lati loo mu won,
ki won le fi won jofin.
Iwadii fi ye wa pe ni nkan bi
aago mesan aabo ale ojo naa tawon olopaa de ibi ti won ni won ti n dana, ni won
doju ija ko won towo si te Chukwudi ati Nwoke nigba tawon yooku juba ehoro..
Titi di asiko yii lawon olopaa si n wa
awon to ti won salo naa, sugbon ti omisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu si
seleri pe ko sibi tawon odaran naa le gba towo awon ko nit e won.
O so pe awon ohun ija oloro orisirisi
bii iso, ibon Pump action meji, ibon ibile kan atawon ota ibon merin ni won ri
gba lowo awon towo te naa.
Bee lo tun ro awon araalu pe ki won ma
se bo enu won nigba ti won ba gbo firi awon afurasi odaran ladugbo won, nitori
aabo emi ati dukia awon araalu lo je oun logun julo.
No comments:
Post a Comment