Pelu bi nnkan se n lo bayii, afaimo
ki oro naa ma kangun sile ejo nitori ti won so pe Gomina egbe olorin juju iyen,
Association of Juju Musician of Nigeria, AJUMN nipinle Ogun, Ogbeni Samuel
Owolabi ko se fee gbe ipo naa sile.
Obey Fabiyi |
Bo tile je ohun taa gbo ni pe okunrin
kan ti won n pe ni Ayo Owolabi lo mu egbe naa ti awon agba ilumooka olorin bii
Oloye Ebenezer Obey Fabiyi, Shina Peters, Wale Thompson atawon mi in wa sipinle
Ogun, sugbon ti won so pe ko si ilosiwaju kankan to de ba egbe naa latigba ti
won ti yan Samuel Owolabi tawon eeyan tun un pe ni Uncle Owo.
Titi di bi a ti n koroyin yi lokunrin
naa ko tii yoju siwa lati wa a so tenu e lori awon esun ti won fi kan, nigba to
je pe funra e lo pe wa pe akoroyin wa pe oro ko ri bee, ati pe oun n bo, sugbon
to si n foni doni, fola dola.
AWIKONKO gbo pe gbogbo ere tokunrin
naa n sa bayii ni lati ma le je ki won yo oun nipo naa, nitori awon oro ibanuje
ti won ni won n so sii pe se lo kan n fi oruko egbe naa se gbajumo, to si fi n
pawo sapo ara e.
Ohun taa gbo ni pe odun kan pere ti
won fun Uncle Owo yi pe ko fi satunse awon isoro tegbe naa n dojuko ko ni pee
pe nitori ti won so pe ko seni to mo pe egbe kan wa to n je egbe AJUMN fun awon
olorin juju.
No comments:
Post a Comment