Beeyan ba je ori
ahun, to ba de ibi ti won ti sinku okan pataki lara awon osere tiata nipinle
Ogun, Oloogbe Isaiah Olurotimi Ayinde topo mo si Abu Olododo to ku leni odun
mokanlelaadota lojo Aje Monde ose to koja yi, yoo banuje pupo.
Abu Olododo |
Bo tile je pe irole
ojo tokunrin naa ku ni won ti sin in nilana igbagbo, nitori ti won so pe ko si
owo nile ti won le fi gboku e lo si motuari fun ojo pipe, sugbon orisirisi
lawon eeyan n so nipa nnkan to sokunfa iku agba osere naa, eni ti won so pe
nise lo foro leran ku.
AWIKONKO gbo pe
kayeefi niku agba osere omo egbe TAMPAN naa si n je fawon eeyan to sunmo paapaa
awon osere tiata, nitori ti won so pe ko figba so pe oun n saisan, eni ti won
loo si tun bawon eeyan dapara titi di nkan ti aago mewa n loo lu lale ojo Sannde
to ku.
Ori aga to jokoo si ninu
yara e lo wa nibi ti won lo n kowe kan lowo ti won ba niwaju e, nile to wa
ladugbo Olorunsogo nilu Abeokuta, ibee naa ni won tun sin in sii.
Bo tile je pe
oloogbe naa kii fi bee ko pa ninu fiimu, eyi ti ko je kawon eeyan fi bee mo,
sugbon to je pe awon gbajumo osere tiata Yoruba paapaa nipinle Ogun ko le fi
sere nitori pe agba akowe iranti (continuity
director) ati asatunto ere (screenplay writer) ni.
Nibi isinku naa |
AWIKONKO gbo pe aisan
eje riru to wa lara Abu Olododo ti le ni odun meta, sugbon ti ko so fenikeni,
won ni kii jina sileewosan fun ayewo, ati pe bawon eeyan se sunmo on to, to fi
mo aburo e, Abayomi to tun sunmo on ko mo iru aisan naa.
Alaaji Waheed Ijaduade
tawon eeyan tun mo si Dimeji, eni to je kawon eeyan gboroyin iku e so f’Alariya
Oodua lojo Isegun Tusde pe oun ati oloogbe naa si soro si nnkan bi aago mewaa
kuseju mokandinlogun (9:41pm) lale ojo Sande ni.
Ninu oro e, o ni “O
ti le ni ogbon odun ti mo ti mo on. Mo lo fun Creative Nigerian Summit kan
niluu Ekoo, eyi tijoba apapo sagbekale e, o seni laanu pe ko raaye lo, sugbon
se lo n bi mi leere nnkan ti a ba bo nibe, nitori pe iru awon nnkan bee lo maa
n nife si nipa ilosiwaju paapaa to ba je mo tise tiata ati lagbo osere.
Lakoko isinku |
“Leyin yen, o tun ni
awon ise kan to fee se pelu ileese OGTV, temi naa si n gbadura pe ki ero yen ma
ku sona bi eefin, nitori pe o ti file sasobora. O n beere nipa awon omo wa to
maa nife lati darapo mo ise yen. Mo ni taa ba rira, aa tubo soro sii nitori pe
o n fe mo nkan ti mo ri sii, ati iha ti mo ko sii, mi o fe maa so gbogbo lori
foonu. Mo si ri ateranse e titi di aago mewaa kuseju mokandinlogun (9:41pm) ale
ojo naa lori Whatsapp mi.”
Ohun taa gbo ni pe
odun meji seyin ni oloogbe naa padanu iya e to je oludasile ijo kerubu ati
serafu nilu Abeokuta. Bo tile je pe iyawo meji ni oloogbe naa fe, sugbon iyawo
kan soso la gbo pe o wa lodo e titi to fi ku, to si je pe omo merin lo fi sile
lo.
No comments:
Post a Comment